Wọn ka oku eeyan tutu mọ gbajumọ babalawo lọwọ l'Ogun, lo ba loun fẹẹ jii dide ni - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, September 2, 2023

Wọn ka oku eeyan tutu mọ gbajumọ babalawo lọwọ l'Ogun, lo ba loun fẹẹ jii dide ni


Ọrọ buruku toun tẹrin nigba tọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun tẹ gbajugbaja okunrin kan to n pe ara rẹ ni babalawo, iyẹn Babatunde Kọlawọle, ẹni ti wọn sọ pe wọn ba oku eeyan tutu lọwọ rẹ, to si loun fẹẹ jii dide ni.

Ọwọ awọn ẹṣọ aabo ilẹ Yoruba ti a mọ si Amọtẹkun, ẹka ti ipinlẹ Ogun lo tẹ Babatunde pẹlu oku eeyanti wọn ṣẹṣẹ pa tan, iyẹn niluu Ado-Odo Ọta, ipinlẹ Ogun.

Agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Ọmọlọla Odutọla to f'idi iṣẹlẹ yii mulẹ ninu atẹjade to gbe sita l'ọsẹ to kọja ṣalaye pe awọn eeyan ni wọn ka oku naa mọ Babatunde lọwọ, ko to di pe wọn lọ fi to awọn Amọtẹkun leti.

O ni b'awọn Amọtẹkun ṣe lọ beere ohun to n fi oku eeyan tutu naa ṣe, niṣe lo sọ pe oun fẹẹ jii dide, bẹẹ lo sọ pe Babatunde ko le sa pato ibi to ti ri oku naa, ati iru ẹni to ku naa.

Siwaju sii ni agbẹnusọ naa sọ pe Babatunde ko jiyan lati sọ pe oun kii ṣe Babalawo, ṣugbọn to sọ pe oun fẹẹ dan agbara oun wo lati ji ou naa dide naa.
 
O l'awọn Amọtẹkun ti fa Babatunde ati oku naa le awọn lọwọ, t'awọn si ti gbe oku naa lọ si mọṣuari fun ayẹwo lati mọ iru iku to pa a.

Bo tilẹ jẹ pe Odutọla ni iwadii ti n lọ lọwọ, bẹẹ lo rọ awọn ara araalu lati wa a wo oku naa, ko ma ba a jẹ pe eeyan wọn ni Babatunde da ẹmi rẹ legbodo lojiji.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI