Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, afaimọ ni ki ọrọ naa ma tun di gbọnmisi-omi-o-to laaarin awọn oloye ati awọn agbaagba ilu Gbagura lori ipo ọba to ṣi silẹ niluu naa, pẹlu bi wọn ṣe n sọ pe awọn kan ti n gbadọde fun ilu.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ ninu atẹjade kan Ọmọọba Ṣharafadeen Ogunwọọlu gbe jade lọjọ kẹẹdogun. Oṣu kẹsan, ọdun ti a wa yii ninu ẹ yii, eyi ti ẹda rẹ tẹ AWIKONKO lọwọ lo ti sọ pe awọn yoo gbe pẹrẹki kana pẹlu awọn to ba fẹẹ gbabọde fun ilu naa, lori ipo ọba to ṣofo.
Ọmọọba Ogunwọọlu to jẹ ọkan lara awọn agba ati alẹnulọrọ lagboole Ẹgiri ti Iddo Gbagura sọ pe oriṣiriṣi iroyin ati atẹjade loun ti ri ka, koda ti awọn redio kan tun sọ ọ wi pe Oloye Bọde Mustapha to jẹ Osi ilu Ẹgba n pe ara rẹ ni apaṣẹ ile Iddo Gbagura, eyi to ni ko le ṣee ṣe.
Baba naa sọ pe ipo ti Oloye Mustapha di mu gẹgẹ bi Osi ilu Ẹgba ati Balogun Ibadan Gbagura, ko fun un ni aṣẹ lati jẹ alakoso igbimọ afọbajẹ tiluu Iddo Gbagura, ati pe boya nitori bo ṣe sunmọ ijọba ipinlẹ Ogun lo fa a, to fi fẹ sọ pe oun ko mọ nnkan ti ofin sọ nipa ilana, iṣe ati ofin oye jijẹ ti wọn gbe kalẹ lọdun 2019, to si fẹẹ fa aburo rẹ ti kii ṣe ọmọ ile Ẹgiri, ti ko si fi ibi kankan tan mọ wọn kalẹ fun ipo ọba Gbagura, pẹlu bo ṣe n leri wi pe oun lẹnu nile ẹjọ.
“Awọn igbesẹ rẹ yii n ṣi awọn eeyan lọkan, a ko si le kawọ gbenu lati jẹ ko maa tẹsiwaju lọnakọna. Oloye Bọde Mustapha, Balogun Ibadan Gbagura lai wo ti atubọtan igbesẹ rẹ, lọ kede iku Oloogbe Ọba Subree Babajide Bakre nipa Balogun miran, to si jẹ pe ologun ni Balogun, kii ṣe alakoso.”
O ni Osi Ẹgba, Balogun Ibadan Gbagura wa ni ipo kẹrin niluu Gbagura, ko si ni aṣẹ kankan ninu aafin Agura tiluu Gbagura, fun idi eyi, o wa n rawọ ẹbẹ si ijọba ipinlẹ Ogun lati tete pe Oloye Mustapha si akiyesi nipa ofin oye jijẹ.
Ati pe ko lọ ka abala keji ninu iwe ofin 'Aafin', ati iwe ofin oye jijẹ ti ọjọ kẹwaa, oṣu kinni, ọdun 2022. Bẹẹ lo tun fi kun ọrọ rẹ pe gẹgẹ bi ilana ati iṣe, Oluwo Iddo nikan lo ni aṣẹ lati pe ipade awọn oloye ilu Gbagura, to si jẹ pe ile Ogboni Iddo nikan ni iru ipade bẹẹ ti le waye, kii ṣe ni aafin rara.
Ṣaaju akoko yii ni iroyin kan ti kọkọ jade sita wi pe gbogbo eto lati yan ọba miran gẹgẹ bi Agura tiluu Gbagura ti bẹrẹ, ati pe Ọjọru tii ṣe Wẹsidee to kọja yii, iyẹn ọjọ kẹtala, oṣu kẹsan, ọdun 2023 ni eto ọhun yoo bẹrẹ ni pẹrẹu.
A gbọ pe awọnn igbimọ afọbajẹ ilu Gbagura ni wọ bẹrẹ eto ifinijọba tuntun naa lẹyin ti iku Ọba ana, Babajide Bakre ti pe aadọrun-un ọjọ.
Iroyin naa sọ pe alaga igbimọ adele ọba, Oloye Bọde Mustapha f'idi rẹ mulẹ pe igbimọ afọbajẹ ti bẹrẹ eto lati mu ọmọ oye ti ipo ọhun kan.
No comments:
Post a Comment