UNGA78-2023: Wo koko ohun marun-un ti Gomina AbdulRazaq sọ nibẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, September 23, 2023

UNGA78-2023: Wo koko ohun marun-un ti Gomina AbdulRazaq sọ nibẹ


Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara sọrọ nibi apero agbaye nni, ti ọdun 2023 to waye ni New York, ṣugbọn sibẹ, wọnyi ni koko ohun marun-un
 
Koko kin-ni-in: Kwara ti mu idagbasoke ba ile-ẹkọ ijọba lati alakọbẹrẹ si ida mejidinlaadọta-le-ni meje (48.7%) laaarin ọdun 2019 si asiko yii.

Koko keji: Aini anfaani si eto ẹkọ to pe ye l'awọn ile-ẹkọ ijọba si dinku lati ida aadọrin-le-ni-mẹjọ (70.8%) si ida mọkanlelaadọta-le-ni-mẹfa (51.6%) lẹyin ogoji ọsẹ ti KwaraLEARN bẹrẹ.

Koko kẹta: •Kwara ti na obitibiti biliọnu naira lori atunṣe si awọn ile-ẹkọ ati ṣiṣe agbekalẹ imọ ẹrọ ti tẹkinọlọji.

Koko kẹrin: Igbelarugẹ si jijẹ anfaani eto ẹkọ to ye kooro fun awọn ọmọ to le ni miliọnu, ti wọn nilo eto ẹkọ jẹ eyi to ṣe koko ni pajawiri.

Koko karun-un: Nina owo sori eto ẹkọ jẹ koko pataki si idagbasoke ju awọn ẹka yooku lọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI