UNGA 2023: Ohun to ṣe pataki lasiko yii ni lati jẹ ki awọn eeyan lẹtọọ si anfaani ẹkọ to ye kooro - Gomina AbduRazaq (Fọto) - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, September 23, 2023

UNGA 2023: Ohun to ṣe pataki lasiko yii ni lati jẹ ki awọn eeyan lẹtọọ si anfaani ẹkọ to ye kooro - Gomina AbduRazaq (Fọto)


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti sọ pe gbigbe anfaani ti yoo jẹ ki eto ẹkọ to ye kooro kalẹ fun awọn to nilo rẹ jẹ eyi to ṣe pataki pupọ fun idagbasoke agbaye, to si nilo amojuto lasiko yii.

AbdulRazaq lo sọrọ naa laipẹ yii nibi ipade agbaye ti United Nations General Assembly ti ọdun 2023, eyi to n waye niluu New York lọwọlọwọ, nibi to ti jẹ ọkan lara awọn to sọrọ.
 
 
 
Bakan naa lo sọ pe o ṣe pataki fun awọn ajọ, ileeṣẹ aladani ;ati fọwọsowọpọ fun idagbasoke eto ẹkọ lagbaaye.

Nibẹ ni Gomina AbdulRazaq ti jẹ o di mimọ pe iṣakoso oun nipinlẹ Kwara ti na owo to le ni biliọnu naira lori ọrọ idagbasoke eto ẹkọ bii mimu awọn ohun amayedẹrun wọlẹ, igbelarugẹ kikọ ẹkọọ igbalode to nipa imọ ijinlẹ ti tẹkinọlọji, ṣiṣe otitọ, ati ẹkọ atigbadegba ti yoo jẹ k'awọn ọmọ ni imọ lati ba ẹgbẹ pe.

 
 
“Lara awọn ohun ti a ti ṣe ni pe a ti ro awọn olukọ lagbara lati le wa ni ibamu ẹlu ilana eto ẹkọ to ye kooro, anfaani f'awọn akẹkọọ lati kẹkọọ, adinku ba aisi nileewe deedee, ati atunṣe si igbaniwọle ti igbalode.”

Ọrọ yii lo waye latari akori ipade naa ti ọdun yii, eyi ti ileeṣẹ Devex Event and New Globe, ṣagbekalẹ rẹ, to si pe ni ‘Ṣiṣe agbeyẹwo wahala ilẹ Afrika and mimu ki awọn ọdọ gbaradi fun ọjọ ọla: ọna abayọ (Addressing Africa’s learning crisis and preparing for a young future: finding solutions).

 
 
AbdulRazag sọrọ nibẹ pẹlu Aarẹ ati oludasilẹ NewGlobe, Shannon May; alakoso ajọ Education Cannot Wait, Yasmine Sherif; alakoso olootu Devex, Richard Jones; igbakeji alakoso Centre for Universal Education, Brookings Institution, Jennifer O’donoghue; ọmọ ẹgbẹ pataki ni Stanford University, Eric Hanushek; ati alakoso agba, Africa CAMFED, Shungu Gwarinda; to fi mọ awọn miran.
 




No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI