Ojulowo ọmọ Mushin ni mi, ṣugbọn Saheed Oṣupa ni ọga mi latilẹ - Tọpẹ Nautical - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, September 15, 2023

Ojulowo ọmọ Mushin ni mi, ṣugbọn Saheed Oṣupa ni ọga mi latilẹ - Tọpẹ Nautical


Bi wọn ba n sọ nipa awọn olorin Fuji ti ogo wọn tan daadaa, ti wọn si tun jẹ onitẹriba fun agba, odu ni Alaaji Tọpẹ Nautical, kii ṣaimọ f'oloko, to si wa lara awọn onifuji ti aye tun n gba tiẹ daadaa lasiko yii.
 
Laipẹ yii ni Tọpẹ Nautical, ẹni ti wọn tun n pe ni ọmọ Iya Aye gba ẹgbẹ awọn akọroyin lede Yoruba, League of Yoruba Media Practitioners lalejo niluu Ekoo laipẹ yii. Nibẹ lo ti tu pẹẹrẹpẹẹrẹ ọrọ nipa irin ajo rẹ sidi iṣẹ orin Fuji, ati awọn nnkan miran.
 
Ẹ ka bi ifọrọwerọ naa ṣe lọ;

Bawo ni Iya Aye ṣe wọ orukọ yin?
Ṣe ẹ mọ pe bi Iya eeyan ba ku, iya naa lo ma n ku, mi o fẹ ki a fa a gun.

Iya o si mọ, gbogbo awọn iya to ku, iya yin naa ni?
Bẹẹ ni

Laipẹ ni a ri yin nile Alaaji Saheed Osupa?
Bẹẹ ni mo lọ sile ọdun ni. Ṣe ẹ mọ pe ọga mi ni, lati ọjọ ti ti pẹ, bẹẹ naa ni ọga ni Wasiu Alabi, lọjọ to tipẹ.

Nnkan to ṣẹlẹ ni pe ṣe ẹ ri nigba mii-in bi eeyan ṣe maa n ro bo ṣe fẹẹ ni ti Ọlọrun a jẹ ko ri bakan, nidii iṣẹ fuji yii, awa ti n reti awọn igbesẹ kan, Igbesẹ ti Alaaji Saidi Oṣupa n gbe lẹnu ọjọ mẹta yii n wu emi funra mi lori.

O lọ si ọdọ Pasuma, o lọọ ki wọn fun ti mama wọn to di Oloogbe, O wu mi lori gan-an ni, ni mo fi sọ pe ọga yii. ọga daadaa ni to n fẹ ki alaafia joba nile fuji.Awọn nnkan wọnyii ti irẹpọ ba ti waye laarin awọn ọga wa, awokọṣe wọn ni awa ta a n bọ lẹyin wọn yoo maa wo ti a o fi maa ṣiṣẹ, nitori awọn to n bọ lẹyin ti wa naa. Ni kikun, iyẹn ni ko ni jẹ ki iṣẹ fuji parẹ.

Awa la ti n gbẹnu le aadọta ọdun bayii, awọn Paso naa ni wọn wa lọjọ ori ti wọn wa. Awọn wo ni a wa fẹẹ fi fuji yii silẹ fun. Nigba to ba jẹ pe gbogbo igba ija, awọn igbesẹ ti Alaaji Saidi gbe yii wu mi lori gan-an ni. Ohun lo fa sababi ti emi naa fi lọ ba wọn ti mo fi lọ bẹ wọn.

Ṣe igbesẹ ti Oṣupa gbe lati lọọ ba Pasuma, lo ta yin nidii lati lọ ba nile?
Latilẹ ọga mi ni Saidi Osupa, itan wa ko ṣee fi pamọ, ti gbogbo awọn aye mọ. Ati pe awọn ara kan ti mi o fẹẹ ma tun sọ mọ. Ṣugbọn ori ẹ ni pe bi eeyan ba bi ọmọ mẹta, to ba tiẹ fẹran ọkan ju, waa fi ọgbọn ṣe, ko nii ma yanna bẹẹ loju wọn, bigba to jẹ pe awọn yooku naa ko ja mọ nnkankan ni.

Bi emi ṣe wa yii, onikaluku lo mọ ibi to ti n bọ, ọmọ Mushin ni mi, ibẹ ni wọn bi mi si, ti mo si dagba si, mi o ni lati sọ pe mo fẹẹ lọ si Ajegunlẹ lati mọ nnkan ti wọn ṣe nibẹ, Emi ati Saidi Oṣupa ti mọ ra tipẹ.

Nigba ta a wa lọdọ wọn, emi Sardon 2, nibẹ ni. Iyẹn Kamọru, amọ wọn mu Muri Thunder, wa ba emi nibẹ ni. O ni bawọn kinni yẹn ṣe lọ nigba naa, gẹgẹ bi awọn agba ṣe maa n sọ, ohun to ba wu ọba lo le fawọn ẹru ẹ ṣe, Ọlọrun ma ṣe wa ni ẹru. Bi emi ṣe maa n ronu gẹgẹ bi ọmọ igboro, mo kan roo pe nigba yẹn ni pe ọmọ jẹ ki n sunmọ ẹyin, ko si ori waa nibẹ.

Bi awọn wo?
Ohun to ṣẹlẹ ni pe mo ti sọ fun alaye lọjọ ti mo lọ sibẹ, mi o fẹ tun maa pada sẹyin, nitori bi agboole fuji ṣe n lọ, mi o fẹẹ sọ nnkankan to le da wahala silẹ. Emi o kii ṣe alabosi, ko si ẹni ti mi ko le sọrọ loju ẹ. Ohun to si sẹlẹ ko ṣe fii pamọ, nigba ti awa mẹta wa lọdọ Oṣupa nigba naa, gbogbo wa la fẹ ni ẹbi, taa si fẹẹ jẹ eeyan nidii iṣẹ fuji. Nigba taa si ri pe ẹnikan ti wọn fẹran ni wọn da yọ sọtọ, gbogbo ẹtọ ati ipolowo to yẹ ki a ma jẹ ni alaye n ṣe fun Muri.

Ohun si lawọn eeyan n ri, ko si ọmọ Oṣupa ti ko mọ orin kọ.Eyi ti alaye fi han awọn eeyan, oun ni wọn n ri, ti wọn jẹ bi ṣawama.iyẹn dun mi, to si mu mi fa sẹyin, ti mo si tẹsiwaju. O ti ṣẹlẹ tipẹ o, o ti n lọ bi ọdun mẹwaa ti emi ti kuro ni mo sọ .igba to ṣẹlẹ gbogbo wa ko tii ṣe ju rẹọọdu meji si mẹta lọ. Gbogbo igba taa wa ti wọn ko tii ya iṣẹ fun wa, olorin ni wa, ṣugbọn ẹyin ọga wa ni a wa.

Mushin ni ẹ wa, ti ẹ ti n kọrin, torukọ ti yọ, ki lo de ti ẹ ko fi jokoo sọdọ Pasuma, to jẹ pe ọdọ Saidi ni ẹ lọ?
Ṣe ẹ ri emi, ṣọọṣi ni mo ti bẹrẹ iṣẹ orin temi, ni Mushin nigba naa, ibi t'awa olorin ti maa n kọrin pọ, o si maa fẹẹ jọ ara wọn, emi si maa n fẹ ki nnkan ko yatọ. Gbogbo igba ti mo n sọ yii ti mo dọmọ onifuji, lẹyin ti mama mi ku ni mi di ọmọọta, gbogbo igba ti wọn wa laye, ile ni mo wa o.

Emi maa n lọ si Ajegunlẹ, nitori mo maa n kaakiri ọmọ igboro ni mi, mo maa n lọ sibi ti oṣupa ti maa n kọrin, mo rii pe mo sunmọ wọn lẹyin ti wọn ṣe orin kan ti wọn gbe wọn wa si mushin. Fun ara mi ni mo lọọ sọdọ ẹ, ti mo lọ fi ara mi han, oun kọ lo fun ni oṣupa keji o,nitori nnkan tawọn eeyan fi mọ mi nigba naa ni. o si gba bẹẹ. Igba to ya, ṣe ẹ mọ pe eeyan maa n gbọn si nidii iṣẹ yii, emi naa ri awọn to fẹẹ ran mi lọwọ ṣe rẹkọọdu, ni mo waa roo pe ko yẹ ki n maa ṣe oṣupa keji, nitori ko si nnkan ti mo le maa fọwọ bo, orukọ ti mo maa jẹ bayii ko Tọpẹ Nautical ki n ma fi nnkankan si. mo ṣe rẹkọọdun kan nigba naa confirmation, awọn eeyan si gba a.

Ni gbogbo igba naa o loju nnkan teeyan gboya fun lati sọ tabi ṣe, nigba ti mo fẹẹ ṣe rẹkẹẹdu yẹn. Awọn eeyan lo gbe e kalẹ, o si n lọ. Nnkan to ko jẹ ki n duro ni mushin ni mo n sọ fun yin yii o.

Ki n to kuro ni Muṣhin Paso jẹ ẹni to dara si mi, emi nikan kọ, atawọn onifuji yooku ni. Ti a maa n ri ile ẹ wọ daadaa, to ba ti wọ ibẹ bayii, waa rẹrin in jade ni. Bi emi tiẹ ṣe wa yii, mo n ṣe ipata gan an ni, aimọye ẹjọ ni Paso ti ba mo yanju.

Ko to di pe Paso kuro ni Muṣhin, to n gbe ni Isọlọ,awa ṣe ipata gan-an ni, ọjọ kan ni Paso pe mi pe ṣe orin lo fẹẹ maa kọ ni tabi ija lo fẹẹ maa ja. Ẹgbọn gidi lo jẹ si mi, ko to di pe mo tun lọ wo nnkan ti wọn n ṣe ni Ajegunlẹ.

Nnkan ti mo kọ lara Oṣupa ṣi wa lara mi, nnkan ti mo kọ lara Paso naa si wa lọwọ mi. Nitori fuji ta an ṣe yii naa, eeyan gbọdọ kọgbọn kaakiri ni,wọn fun mi ni nnkan ti mo fẹẹ, emi ri nnkan ti mo fẹẹ lọdọ wọn, wọn kọ mi bi eeyan ṣe n ṣe orin, wọn fun wa ni igboya lati le gbe orin kalẹ. Bawọn purodusa ba fẹẹ fun ẹ niṣẹ, bi wọn ba ri bi iwọ gan-an ṣe n kọrin, wọn a kọkọ sun mọ ẹyin.wọn a jẹ ko danmọran, mo ri nnkan ti mo n fẹ lọdọ oṣupa. Nnkan kan to mu mi sun mọ ẹyin naa ni mo ti sọ saaju.Paso ti ẹ n pariwo, to ba debi bayii, yoo di ẹgbẹ gbogbo wa ni, iwọ to ba ri lo ri, to baa wa lọ sibi to ba wa ko ri tiẹ ro. Emi tiẹ fẹran bi agbo fuji ṣe n ri bayii, ko si ikunsinu,gbogbo dun ni.

Bawo waa ni ẹyin ati Muri Thunder?
Awọn eeyan kan maa n sọ isọkusọ ni, ẹ o le beere lọwọ ẹ, ko ni oun ati Tọpẹ ja laelae, a nija, igba ti mo sọ pe mo sun sẹyin lọdọ Oṣupa, ko pẹ ti mo kuro nibẹ ni mo gbọ pe muri n bu saidi Oṣupa, ara mi o gba, mo bẹrẹ si nii da a lohun, igba ti mo ṣe diẹ, ni mo ba pinnu lati kuro nibẹ, ti mo kọju mọ iṣẹ mi.

Bawo lo ṣe ri lara yin pe ẹ ri eeyan bi Wasiu Ayinde, nibi apejẹ lọjọ ti Tinubu gbajọba?
Ṣe ẹ ri awọn nnkan ta n reti pọ, diẹdiẹ naa ni. Lakooko yii, Aarẹ wa Tinubu oloolufẹ fuji ni wọn, lati aye Sikiru Ayinde Barrister, ki Ọlọrun fọrunkẹ wọn, nisinyii, Mayegun lo wa nibẹ, ki Ọlọrun jẹ ka ri wọn pẹ.

Mo ri pe bi wọn ṣe wa nibẹ, ọlọpọlọ pipe ni Wasiu Ayinde, mo nigbagbọ pe wọn yoo ti maa gbe igbesẹ kan pe eeyan ti wa lo nibẹ, oun ni apẹẹrẹ eyi ti ẹ sọ lẹẹkan, ṣe ẹ mọ pe onifuji kankan ko ṣe iru nnkan bẹẹ. A tun fẹ nnkan to le ṣe wa ni anfaani.

Nibo lọpọn orin sun Tọpẹ Nautical de?
Ẹ jẹ ka ma dupẹ na, mo ti lọ South Africa, Ghana, Dubai, awọn kan wa ti mo fẹẹ sọ nibi, to maa ṣẹlẹ lọdun yii, nitori nnkan ta a ba bo, lo ma n niyi. Asiko ta a wa yii, mo n lọ so Egypit, Kenya, ilẹ Africa ni, mi o ti lọ si London ri, mi o ti lọ si Amẹrika

Nigba ti wahala bẹ silẹ laarin Arabanbi ati Olufimọ. N jẹ ko fẹẹ fa yin laṣọ ya?
Haa!, O lagbara gan–an ni, nitori mi o fẹẹ da si, mi o ṣe mejeeji, nitori mi o fẹẹ ni wahala pẹlu ẹnikẹni, o fẹẹ dabi ẹni pe Tọpẹ Nautical, ko mọ orin kọ mọ nigba naa. Nigba ti Pasuma da ọga nla silẹ, emi ni onifuji akọkọ to kọkọ fọwọ si, mo ni o se sọ, idi ni pe nnkan to ṣe sọ laduugbo mi, tikẹẹti ọmọ muṣhin, ni mo fi wọle, kin ni yẹn ti di igun nigba naa, to ba ṣe ọganla, wọn ko ni mọ pe o mọ orin kọ, to ba si se ọga nla bakan naa ni, ọtẹ naa ni gbogbo ẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI