Ominira: Ko nii si ayẹyẹ rẹpẹtẹ kankan - Ijọba Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, September 28, 2023

Ominira: Ko nii si ayẹyẹ rẹpẹtẹ kankan - Ijọba Kwara


Ijọba ipinlẹ Kwara ti kede sita wi pe awọn ko nii ṣe ayẹyẹ ọdun ominira ti ọdun 2023 yii ni alariwo, niṣe ni wọn wọn yoo rọra ṣe e.

Gbogbo ọjọ kinni, oṣu kẹwaa ninu ọdun ni ayẹyẹ ọdun ominira lorileede Naijiria, ti awọn araalu ati ijọba si maa n ranti rẹ.

Ninu atẹjade ti Kọmiṣanna f'ọrọ eto ikansira-ẹni n'ipinlẹ naa, Arabinrin Bọlanle Olukoju fi sita laipẹ yii lo ti jẹ ko di mimọ pe ko nii si ayẹyẹ.

O sọ pe eyi ni lati fi bọwọ fun atunṣe ti ijọba n ṣe lọwọ lori idagbasoke eto ọrọ aje 

Bakan naa lo gba araalu lamoran lati lo akoko ayajọ ọdun ominira naa lati fi gbadura fun Ipinlẹ naa, orileede Naijiria ati gbogbo agbaye lapapọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI