O ma ṣe! Wọn ba oku Deborah, akẹkọọ FUOYE nibi ti wọn sin-in si - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, September 9, 2023

O ma ṣe! Wọn ba oku Deborah, akẹkọọ FUOYE nibi ti wọn sin-in si


Ọjọ buruku, eṣu gbomimu l'Ọjọru tii ṣe Wẹsidee, ọsẹ yii jẹ niluu Ọyẹ-Ekiti, ipinlẹ Ekiti nigba ti wọn ṣadede ri oku akẹkọọbinrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Atanda Modupẹ Deborah nibi ti wọn sin-in si.
 
Deborah to wa ni ipele akọkọ, ẹka ikẹkọọ awọn nọọsi, iyẹn Nursing Department, stream A, Faculty of Basic Medical Science nile ẹkọ fasiti Ọyẹ Ekiti tii ṣe Federal University of Oye Ekiti (FUOYE) la gbọ pe o deede di awati lalẹ ọjọ Aje tii ṣe Mọnde, ọsẹ yii, ọjọ kẹrin, oṣu kẹsan, ọdun 2023.

Nigba ti wọn yoo ri oku rẹ, o ṣe awọn eeyan ni kayeefi wi pe wọn ti yọ oju rẹ mejeeji lọ.
 
Wọn ni kilaadi lo dagbere wi pe oun n lọ lati lọ kawe, ti wọn si l'awọn ọrẹ rẹ ti wọn jọ n gbe inu ile ko rii lasiko to yẹ ko pada sile, eyi lo jẹ ki wọn bẹrẹ sii wa a kaakiri.

Fun bi ọjọ meji gbako ni wọn fi wa a kaakiri, koda ti wọn l'awọn ọlọpaa naa tun gbiyanju agbara wọn, ko to di pe wọn pada ba oku rẹ ninu saare ti wọn sin-in si lẹyin yara ikẹkọọ rẹ.
 
Olugbaniwọle sile ẹkọ naa, Mufutau Ibrahim nigba to n sọrọ nirọlẹ Ọjọru tii ṣe Wẹsidee, o ni kayeefi lo jẹ fun wọn, to si l'awọn ti paṣẹ fun gbogbo akẹkọọ lati gba ile wọn lọ fun igba diẹ.
 
Ibrahim ni awọn oṣiṣẹ eleto aabo ati agbofinro ti bẹrẹ iṣẹ iwadii wọn, lati mọ awọn to pa Deborah, to si ni ọwọ ti tẹ awọn eeyan meloo kan lati fọrọ wa wọn lẹnu wo.
 
Bẹẹ lo fi kun un pe ile-ẹkọ naa ko nii fọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ iku Deborah, nitori to ṣe wọn ni kayeefi pupọ, to si lawọn ti ọrọ naa ba ṣi mọ lori yoo pada foju winna ofin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI