O ma ṣe o! Eeyan mẹta ku iku ojiji bi mọto wọn ṣe mori wọnu odo l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, September 3, 2023

O ma ṣe o! Eeyan mẹta ku iku ojiji bi mọto wọn ṣe mori wọnu odo l'Ogun


Bi ẹlẹkun ṣe n sunkun, bẹẹ l'awọn eeyan n barajẹ gidigidi nigba ti awọn omuwẹ n doola ẹmi awọn mẹta kan ti mọto wọn gbokiti wọnu odo Ọmọ to wa lopopona marosẹ Ekoo si Benin.
 
Ọjọ Satide, Abamẹta to kọja yii la gbọ pe mọto ayọkẹlẹ Sienna ti nọmba idanimọ rẹ jẹ APP830HX gbokiti wọnu odo naa, ni nnkan bi aago mọkanla aabọ aarọ.
 
Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ eleto oaabo oju popona t'ijọba apapọ, Federal Road Safety Corps sọ pe afọwafa ni ijamba naa, nitori pe ere asapajude lo ṣokufa iku ojiji t'awọn eeyan naa pade.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ninu atẹjade ti agbẹnusọ fun ajọ FRSC nipinlẹ Ogun, Florence Okpe fi sita, o ni ọpẹlọpẹ awọn omuwẹ to wa nitosi odo naa, lo jẹ ki wọn tete ri ẹnikan ninu awọn mẹrin to wa ninu mọto naa yọ jade lai ku.
 
O ni oku ko ba di mẹrin, ṣugbọn to ni gbogbo igbiyanu awọn omuwẹ lati yọ awọn eeyan naa jade lasiko lo ja si pabo, to mu k'awọn mẹta gbabẹ sọda sọrun alakeji.
 
Siwaju sii lo sọ pewọn ti gbe ẹnikan ti wọn ri yọ jade lọ si ọsibitu Hope to wa ni J4 fun itọju to pe ye, ti wọn si ti ko awọn oku mẹta naa lọ si mọṣuari ọsibitu to wa niluu Ijẹbu Ode.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI