Nitori iṣẹ Yahoo mi ti ko lọ deedee ni mo ṣe dọgbọn sii - Miracle, akẹkọọjade Unilag ti wọn ba ori eeyan ninu yara rẹ jẹwọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, September 2, 2023

Nitori iṣẹ Yahoo mi ti ko lọ deedee ni mo ṣe dọgbọn sii - Miracle, akẹkọọjade Unilag ti wọn ba ori eeyan ninu yara rẹ jẹwọ


Beeyan ba wa nibi ti gendekunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Miracle Nwankwo ti n ka boroboro, yoo mọ pe ọdaju eeyan paraku, ati pe lara awọn ọdọ ti wọn ko fẹẹ ṣiṣẹ, ṣugbọn ti wọn n wa owo ojiji ni.
 
Miracle, ọkan lara awọn akẹkọọjade fasiti ipinlẹ Ekoo, iyẹn Unilag la gbọ pe ọwọ palaba rẹ segi lori ẹsun wi pe o gbe ori eeyan pamọ sinu ikoko ninu yara rẹ.
 
Yatọ si Miracle, ọwọ tun tẹ babalawo rẹ, Ifeanyi Njoku niluu Ijoko, ipinlẹ Ekoo.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni awọn kan lo ta ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekoo lolobo wi pe wọn kofiri ohun to jọ ori eeyan ninu ikoko kan ti Miracle gbe pamọ sinu ile rẹ.

Loju ẹsẹ ni wọn l'awọn ọlọpaa ti lọ yẹ Miracle wo, ti wọn si ba ikoko ọhun to gbe ori eeyan pamọ si, eyi ti wọn lo n lo fun iṣẹ jibiti ori ayelujara, iyẹn Yahoo-Yahoo to n ṣe.
 
Miracle nigba to n sọrọ ṣalaye pe ọdun karun-un ree toun ti n ṣiṣẹ jibiti ori ayelujara, ṣugbọn ti iṣẹ naa ko lọ deedee f'oun mọ.
 
O nibi toun ti n wa ọna abayọ loun ti ṣalabapade Njoku, ẹni to jẹ ogbologbo nidi iṣẹ babalawo, to si loun lo ran oun lọwọ latigba naa, lai mọ pe aṣiri maa pada tu sita.
 
Njoku ninu ọrọ tiẹ naa sọ pe lotitọ loun ṣẹṣo owo fun Miracle, ati pe ọwọ ẹnikan t'awọn jọ n ṣiṣẹ babalawo loun ti ra ori oku toun fi ṣiṣẹ fun Miracle.
 

A gbọ pe iṣẹ iwadii ti bẹrẹ, bẹẹ l'awọn ọlọpaa ti f'oju wọn ba ile-ẹjọ lori ẹsun ipaniyan ati gbigbe ẹya ara eeyan pamọ lọna aitọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI