Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun ṣabẹwo si alaṣẹ ileeṣẹ Adron Homes lori eto aabo to pe ye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, September 14, 2023

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun ṣabẹwo si alaṣẹ ileeṣẹ Adron Homes lori eto aabo to pe ye


Lati le mu ki ajọṣepọ to dan mọnran wa laaarin ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ati awọn araalu, ọga ọlọpaa ipinlẹ naa, Abiọdun Alamutu ti ṣabẹwo si baba isalẹ ẹgbẹ awọn ajọ to n ri ṣorọ araalu ati ọlọpaa, iyẹn Police Community Relations Committee, PCRC, Aarẹ Adetọla EmmanuelKing lori ipa rere to n ko lori eto aabo.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ile Aarẹ EmmanuelKing to jẹ alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ Adron Homes and Properties Limited to wa niluu Iliṣhan-Rẹmọ ni ọga ọlọpaa naa ti lọ ṣabẹwo sii l'Ọjọru tii ṣe Wẹsidee, ọsẹ yii.
 
Nigba to n gba ọga ọlọpaa lalejo, Ọtun-Akilẹ Rẹmọ naa sọ pe idunnu nla lo jẹ foun pe ọga naa ri ipa ribiribi toun n ko lawujọ, paapaa lori eto aabo, to si lo jẹ oun iwuri foun lati tun ṣe sii.

Ọga ọlọpaa ninu ọrọ rẹ dupẹ lọwọ Aarẹ EmmanuelKing fun ọwọ ifẹ to na s'oun, eyi to mu k'awọn araalu fọwọsowọpọ pẹlu oun latigba toun ti di ọga ọlọpaa, ni nnkan bi oṣu meloo sẹyin.
 
“Inu mi dun lati wa nibi ipade yii lonii, mo si tun wa dupẹ fun ifẹ atigbadegba latigba ti wọn ti gbe mi wa s'ibi gẹgẹ bi kọmiṣanna. Iriri nla gidi lo jẹ fun mi pẹlu ẹgbẹ PCRC nipinlẹ Ogun ati nilẹ Yoruba lapapọ, eyi to mu ki iṣẹ rọrun fun mi.

“MO wa sibi pẹlu ọrọ gidi, paapaa lati ba mi sọ f'awọn ọmọ ẹgbẹ pe mi o ni ko iyan wọn kere. Ilẹkun mi ṣi silẹ fun ẹnikẹni. Lai si ifọwọsowọpọ wọn, a ko le ṣe aṣeyọri, to n mu ki ipinlẹ Ogun di gbigbe.

Ninu ọrọ tiẹ, Alaṣẹ Adron to tun jẹ baba iṣale ẹgbẹ naa nilẹ Yoruba sọ pe “Idunnu nla lo jẹ fun mi lati gba ọga ọlọpaa lalejo nile mi. O fi han pe ẹ mu ọrọ wa lokunkundun, paapaa ipa ti a n ko ninu ọrọ eto aabo ilẹ yii.
 
“Mo tun wa fi n da a yin loju bayii pe emi gẹgẹ bii baba iṣalẹ ẹgbẹ PCRC ati oludasilẹ ileeṣẹ Adron Homes, maa tubọ maa ṣe iranwọ fun ileeṣẹ ọlọpaa lori eto aabo to dan mọran, fun igbadun araalu.”













No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI