Johnpaul fi jibiti gba mọto miliọnu mẹjọ naira l'Ekoo, lo ba laye lo n ṣe oun niwaju adajọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, September 9, 2023

Johnpaul fi jibiti gba mọto miliọnu mẹjọ naira l'Ekoo, lo ba laye lo n ṣe oun niwaju adajọ


Ọrọ buruku toun tẹrin nigba ti Baale ile ẹni ọdun mẹrindinlaadọta kan,
Ekenedilichukwu Johnpaul n sọrọ niwaju adajọ, to si loun ko jẹbi alaye wi pe aye lo n ṣe oun, toun fi f'ọgbọn lu jibiti mọto.
 
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekoo ni wọn foju Johnpaul ba ile-ẹjọ Majisireeti to wa lagbegbe Ikẹja niluu Ekoo l'ọjọ Ẹti tii ṣe Furaidee, to kọja yii, lori ẹsun wi pe o fi ọgbọn jibiti gba mọto bọọsi igbalode Toyota Hiace ti owo rẹ ko din ni miliọnu mẹjọ naira.
 
Ẹsun jibiti, ole jija ati ilọnilọwọgba ni wọn fi kan Johnnpaul, ẹni to n gbe lagbegbe Igala Estate, Ejigbo nipinlẹ Ekoo niwaju Onidajọ M. F. Onamusi.
 
Nigba to fẹsun kan Johnpaul, agbefọba Innocent Odugbo,sọ pe ọjọ kejidinlogun, osu kejila, ọdun 2019 lọkunrin naa lọ si Ladipọ to wa ni Mushin lati gba mọto naa lọwọ Ọgbẹni Ikechukwu Esemonu.
 
O ni Ikechukwu gbe mọto naa sile Johnpaul lati ba oun ta a, pẹlu igbagbọ to ni ninu ẹ.
 
Latigba naa ni wọn sọ pe Johnpaul ti bẹrẹ sii gun mọto ọhun kaakiri, to si n sọ f'awọn eeyan pe oun ṣẹṣẹ ra a ni. Ko pẹ lo tun ta mọto naa, to si tun bẹrẹ sii fi owo rẹ jaye familete ki n tutọ kaakiri.

Gbogbo akitiyan Ikechukwu lati gba owo rẹ lọwọ Johnpaul lo ja si pabo, ko to di pe o gba teṣan ọlọpaa lọ lati fi to wọn leti, ti ọwọ si pada tẹ ẹ.
 
Ẹsun yii ni agbefọba Odugbo sọ pe o tako iwe ofin ọdaran tipinlẹ Ekoo tọdun 2015 ni abala 287,314 ati 411.
 
Onidajọ Majisireeti M. F. Ọnamusi ti wa  a paṣẹ pe ki Johnpaul lọ san miliọnu kan naira pẹlu oniduro meji lati gba beeli ara rẹ, ki wọn si pada wa lọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹsan ti a wa yii fun igbẹjọ miran.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI