Ẹsẹ ko gbero niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun l'ọjọ Abamẹta tii ṣe Satide, ọjọ kẹrin, oṣu kẹsan, ọdun ti a wa yii, nigba ti Ọọni Ile-Ifẹ, Alayeluwa Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi wọ ilu naa fun ti ayẹyẹ iwuye Ọba Oluṣẹgun Alexander Macgregor kinni-in, Olu Orile-Ilawọ.
Yatọ si Ọọni Ifẹ, Olu tiluu Warri, Utieyinoritsetsola Emiko Ogiame Atuwatse III; Olubadan tilẹ Ibadan, Ọba Lekan Balogun ati awọn miran ni ko gbẹyin nibẹ.
Nibi ayẹyẹ naa ni Ọọni Ile-Ifẹ ti gba Ọba Macgregor lamọran lati lo awọn aṣeyọri lorileede Canada, United Kingdom ati Amẹrika lati fi mu idagbasoke ba ilu Orile-Ilawo ati agbegbe rẹ lapapọ, fun ilọsiwaju, paapaa lẹka eto ilera too ti jẹ akọṣẹmọṣẹ.
Bẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu karun-un, ọdun yii ni Gomina Dapọ Abiọdun gbe ade le Ọba Macgregor lori gẹgẹ bi olu tiluu Orile-Ilawọ tuntun, iyẹn niluu Ẹlẹgunmẹfa, lẹyin ti Ọba ana, Ezekiel Alabi waja.
Ọọni Ifẹ fi idunnu rẹ han si Ọba Ọjọgbọn MacGregor lori bo ṣe fi awọn igbe aye igbalode ati aṣeyọri rẹ silẹ niluu Oyinbo, to si gba lati darapọ mọ ipo ori ade.
O ni ki ọba tuntun yii ko gbogbo araalu mọra, paapaa awọn ti wọn jọ du ipo naa mọra, lai yọ ẹnikẹni silẹ, lati le ṣe aṣeyọri to lọọrin laaarin ilu.
Bakan naa lo rawẹbẹ s'awọn araalu lati gbaruku, ki wọn si fọwọsowọpọ pẹlu Ọba wọn fun idagbasoke ati ilọsiwaju ilu Orile-Ilawọ.
No comments:
Post a Comment