Ijọba ipinlẹ Ọṣun ti paṣẹ wi pe ki wọn ti ile-ẹkọ gbogboniṣe tiluu Iree pa fun ọsẹ meji gbako, to si tun ni ohunkohun ko gbọdọ ṣẹlẹ nibẹ fun ọsẹ meji naa.
Aṣẹ yii la gbọ pe o waye lẹyin ti ọga agba ile-ẹkọ naa tẹlẹ ti wọn jawe lọ rọkunle fun pada sẹnu iṣẹ rẹ, eyi to fẹẹ da wahala nla silẹ.
F'awọn ti ko ba mọ, ọga ile-ẹkọ naa, Ọmọwe Tajudeen Ọdẹtayọ ni ijọba sọ pe ko lọ rọkunle fun lọjọ kẹrinlelogun, o'su keje, ọdun yii, lẹyin ẹsun aṣemaṣe ati ṣiṣe owo kumọkumọ.
Eyi lo gbe Ọdẹtayọ lọ sile ẹjọ ajafẹtọọ, National Industrial Court to wa niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ, ti ile-ẹjọ naa si paṣẹ pe ko ṣi lọ maa tẹsiwaju gẹgẹ bi ọga agba.
Ninu atẹjade ti kọmiṣanna fọrọ eto ẹkọ, Dipọ Eluwọle fi sita l'Ọjọbọ tii ṣe Tọside, lo ti ki gbogbo oṣiṣẹ ati akẹkọọ patapata gba ile wọn lọ fun ọsẹ meji gbako.
“Eyi ni lati fi to gbogbo eeyan, paapaa awọn oṣiṣe ati akẹkọọ ile-ẹkọ gbogboniṣe ti Iree lati lọ sile fun isinmi ọlọsẹ meji, lai fi akoko ṣofo.
“Isinmi yii ṣe pataki pupọ lojuna lati gba alaafia laaye ninu ọgba naa lẹyin ti ọga agba ti a ti le lọ sile, Ọmọwe T. A Ọdẹtayọ pada lati f'ipa gba ipo rẹ tẹlẹ.
“A tun ni lati fi to o yin leti pe a ti ko gbogbo owo to wa ninu apo owo ile-ẹkọ naa kuro, to si di dandan lati jẹ ki awọn eeyan mọ pe wọn gbọdọ tẹle ilana yii.”
Ṣaaju asiko yii akọwe agba lẹka ileeṣẹ to n ri sọrọ eto ẹkọ, Kẹhinde Jimọh ti gbe atẹjade sita lọjọ kẹrinlelogun, oṣu keje, ọdun 2023 wi pe ki Ọdẹtayọ lọ rọkunle, to si fi Alabi Kẹhinde rọpo rẹ lati ṣe adele.
Ọjọbọ tii ṣe Tọside ni Ọmọwe Ọdẹtayọ pada si ile ẹkọ naa lati bẹrẹ iṣẹ pada, lẹyin idajọ ile-ẹjọ ajafẹtọọ.
Nigba to n gbe aṣẹ rẹ kalẹ, Onidajọ Ọpẹloyẹ Ogunbọwale sọ pe oun da Gomina Ademọla Adeleke ati awọn mẹrinla miran lọwọ kọ lati yan ọga agba miran fun ile-ẹkọ naa.
Bakan naa ni Onidajọ Ogunbọwale tun paṣẹ pe ki Adeleke ati awọn eeyan rẹ ko gbọdọ da si ọrọ ile-ẹkọ gbogboniṣe naa, titi digba ti igbẹjọ miran yoo tun waye lọgbọn ọjọ, oṣe kẹwaa, ọdun 2023.
No comments:
Post a Comment