Igbakeji akọwe agba ajọ agbaye - United Nations gbe oṣuba kare fun AbdulRazaq ni New York (Fọto) - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, September 23, 2023

Igbakeji akọwe agba ajọ agbaye - United Nations gbe oṣuba kare fun AbdulRazaq ni New York (Fọto)


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq l'ọjọ Ẹti tii ṣe Furaide, ọsẹ yii ti ṣepade pọ pẹlu igbakeji akọwe agba fun ajọ agbaye, iyẹn United Nations Deputy Secretary-General, Arabinrin Amina Mohammed niluu New York.

Ipade ọhun lo waye lẹgbẹ kan nibi ipade apero agbaye, ẹlẹẹkejidinlọgọrin iru ẹ.

Lara awọn to tẹle gomina AbdulRazaq ni alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ BUA Group, Abdulsamad Rabiu.

Nibẹ ni Arabinrin Mohammed gbe oṣuba kare fun gomina, lori bo ṣe jẹ ki awọn obinrin pọ ninu iṣakoso rẹ, to si ni eyi gan-an ni yoo mu adinku ba ẹlẹyamẹya ninu oṣelu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI