Lojuna lati jẹ ki awọn akẹkọọ ni imọ eto ẹkọ to ye kooro to le jẹ ki wọn ba ẹgbẹ pe, ijọba ipinlẹ Kwara tun ti bẹrẹ sii pin iwe kika ati kikọ lọfẹẹ fun gbogbo awọn akẹkọọ patapata, iyẹn awọn ti wọn wa nile-ẹkọ ijọba.
Yatọ iwe ti ijọ pin yii, wọn tun pin awọn irinṣẹ ere idaraya bii aṣọ, bata, boolu ati bẹẹbẹẹlọ fun awọn akẹkọọ naa, lati le jẹ ki eto ere idaraya wọn ba ti igbalode mu.
AWIKONKO gbọ pe gbogbo ile-ẹkọ iijọba to wa kaakiri ijọba ibilẹ ogun to wa nipinlẹ naa ni wọn gba awọn nnkan wọnyii, eto ọhun to bẹrẹ l'Ọjọbọ tii ṣe Tọsidee, ọsẹ yii.
Eyi lo si waye latari ipinnu Gomina AbdulRahaman AbdulRazaq lati le mu adinku ba ẹru ti awọn obi ati alagbato n gbe lori eto ẹkọọ awọn ọmọ wọn, paapaa latari bi eto ọrọ aje orileede yii ṣe ri.
Gomina AbdulRazaq ti igbakeji rẹ, Ọgbẹni Kayọde Alabi ṣoju fun nibi ifilọlẹ pinpin awọn nnkan ikẹkọọ idẹrun yii ṣalaye pe eto naa ni lati da eto ẹkọ igbalode to ye kooro pada si ipo to yẹ ko wa, ki awọn akẹkọọ tun le ni ilera pipe.
No comments:
Post a Comment