Ẹ woju ọmọ ẹgbẹ okunkun meji tọwọ tun tẹ l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, September 9, 2023

Ẹ woju ọmọ ẹgbẹ okunkun meji tọwọ tun tẹ l'Ogun


Kani kii ṣe pe awọn ọlọpaa tete gbera lọ sibi t'awọn ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun ti n ṣepade lati lọ da wahala silẹ ladugbo Fadahunsi to wa niluu Agbado, ipinlẹ Ogun, o ṣee ṣe ki ariwo ẹkun tun ti sọ.

Awọn kan ni iroyin fi to wa leti wi pe wọn ta ileeṣẹ ọlọpaa lolobo wi pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti korajọ lati lọ da wahala silẹ, eyi ti wọn fẹ fi da igboro ru.

Loju ẹsẹ la gbọ pe ọga ọlọpaa ẹkun Agbado, CSP Adekunle Awoniyi ti gbera pẹlu ikọ rẹ lati lọ koju wọn, ti ọrọ naa si pada di boolọ o yago lọna.
 
Lẹyin o rẹyin la gbọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa juba ehoro, ṣugbọn ti meji ninu wọn pada ha.
 
Sọdiq Idowu, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ati Yusuf Wahab, toun jẹ ẹni ọdun marudinlọgbọn ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹiyẹ lọwọ palaba wọn segi.
 
Awọn mejeeji yii la tun gbọ pe wọn ti n fun awọn ọlọpaa ni iroyin ti wọn n fẹ nipa bọwọ ṣe le tẹ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun to na papa bora, ati awọn alatako wọn.
Ọmọlọla Odutọla to jẹ agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun nigba to n sọrọ sọ pe bi awọn ọlọpaa ẹkun Agbado ba pari iwadii wọn, wọn yoo tare awọn mejeeji si ẹka to n ri sọrọ ẹsun ọdaran, State Criminal Investigation Department.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI