Ẹ wo oju Emmanuel to n pe ara rẹ ni ọga ọlọpaa ipinlẹ Ekoo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, September 16, 2023

Ẹ wo oju Emmanuel to n pe ara rẹ ni ọga ọlọpaa ipinlẹ Ekoo


Ọrọ kan ni awọn Yoruba fi maa da aṣa wi pe 'ori to ba maa jẹ iko, to ba we igba lawaani s'ori, yoo ṣi ṣaa ni lati jẹ ẹ' gẹlẹ lo lọ nibamu pẹlu bọwọ ṣe tẹ ọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Emmanuel, ẹni ti wọn lo n fi iṣẹ ọlọpaa li awọn araalu ni jibiti.
 
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Ekoo, Benjamin Hundeyin gbe jade lọjọ kọkanla, oṣu kẹsan, ọdun ti a wa yii, lo ti sọ pe ọjọ keji, oṣu yii gan-an lọwọ tẹ Emmanuel, iyẹn laago mẹta ku ogun iṣẹju ọsan.
 
O ni niṣe ni yoo lọ s'awọn agọ ọlọpaa, ti yoo si maa sọ fun wọn pe ọga ọlọpaa loun.
 
Hundeyin ni niṣe ni Emmanuel lọ si buba awọn ọlọpaa tiluu Ikorodu lọjọ naa, layi lọ farahan nibẹ pe ọga ọlọpaa loun, ti wọn si gba a tọwọ t'ẹsẹ nibẹ.
 
Nibi ti wọn ti n fọrọ wa a lẹnu wo la gbọ pe wọn ti ṣakiyesi wi pe kii ṣe ọlọpaa rara, bi ko ṣe pe ayederu pọmbele ni. Eyi lo fa a ti wọn fi lọ yẹ inu ile rẹ wo, ti wọn si ba oriṣiriṣi dukia ọlọpaa nibẹ.

Lara awọn nnkan Hundeyin sọ pe awọn ri gba lọwọ rẹ nikaadi idanimọ igbakeji ọga ọlọpaa, aṣọ awọtẹlẹ ọlọpaa, fila ọlọpaa ati ohun ibara-ẹni sọrọ ti Kenwood, Kenwood walkie-talkie.
 
Siwaju sii ni Hundẹyin tun sọ pe ọwọ tun tẹ ẹlomiran, Ibrahim Bello toun naa n pe ara rẹ ni ohun ti ko jẹ, iyẹn lọjọ kẹrin, oṣu ti a wa yii, to si ni ẹgbẹ awọn agbofinro, ẹka ti ilu Ẹpẹ l'Ekoo lo mu ẹjọ rẹ wa f'awọn ko to di pe ọwọ tẹ ẹ.
 
O ni niṣe ni wọn sọ pe Bello n pe ara rẹ ni agbẹjọro ni ile-ẹjọ Majisireeti tiluu Ẹpẹ pẹlu ọpọlọpọ iriri lẹnu iṣẹ, ti wọn ko si mọ ọn ri.
 
Hundẹyin ni aṣọ agbẹjọro wa lara rẹ nigba ti ọwọ tẹ ẹ ninu kootu nigba to lọ gbẹjọro fun onibara rẹ to lu ni jibiti.
 
Igba ti wọn bẹrẹ si ni fọrọ wa a lẹnu wo, ni aṣiri tu wi pe ko gba ile-ẹkọ agbẹjọro kọja rara.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI