Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ Temidire Anigilaje to jẹ ogbologbo afurasi adigunjale niluu Abẹokuta, ipinlẹ naa, to si ti wa lahamọ wọn.
Ninu atẹjade tiagbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ naa, Ọmọlọla Odutọla fi sita lo ti jẹ ko di mimọ pe agbegbe Arẹgbẹ to wa nitosi Ọbantoko niluu Abẹokuta lọwọ ti tẹ Anigilaje.
Odutọla ṣalaye pe awọn ara agbegbe naa lo ranṣẹ s'awọn ọlọpaa wi pe awọn adigunjale ti ya wọ adugbo awọn, ti wọn si nilo iranlọwọ, to si loju ẹsẹ l'awọn ti gbera lọ sibẹ.
Iyalẹnu nla lo jẹ pe b'awọn adigunjale naa ṣe gbọ ohun awọn ọlọpaa ni wọn ti juba ehoro, ṣugbọn to jẹ pe Anigilaje nikan lọwọ tẹ laaarin wọn.
Odutọla ni lẹyin-o-rẹyin ni wọn yẹ gbogbo agbegbe naa wo, ti wọn si ba ẹrọ amunawa jẹnẹretọ ti ṣọọṣi Ridiimu, eyi ti wọn jigbe pamọ sinu igbo.
Ninu iroyin miran to fara pẹ ẹ lọwọ ti tẹ Mutiu Ṣolankẹ lagbegbe Eleweran niluu Abẹokuta, ẹni ti wọn sọ pe wọn ba ibọn ilewọ lọwọ ẹ, ti ko si le ṣalaye ohun to n fi ibọn naa ṣe.
Odutọla ni ori ọkada ni Mutiu wa ti wọn fi daa duro lati mọ iru eeyan to jẹ, ṣugbọn to sọ pe iṣẹ ọlọdẹ loun n ṣe lagbegbe Camp. Igba ti wọn yẹ ara rẹ wo daadaa ni wọn ba ibọn naa, to fi mọ ọta
Siwaju si i ni Odutọla jẹ ko ye wa pe Mutiu ko ni iwe aṣẹ lati maa lo ibọn, fun idi eyi, o ni yoo foju winna ofin.
No comments:
Post a Comment