Alaṣẹ, apaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ Pelican Valley Nigeria Limited, Ọmọwe Babatunde Adeyẹmọ ti sọ pe ko si asiko to dara fun awọn ọmọ orileede Naijiria lati fi owo wọn dokoowo lori ọrọ ile ati dukia si Naijiria, to kọja asiko yii.
O ni asiko ti owo dọla ti lọ soke kọja ohun ti ẹnikẹni ko lero yìí gan-an lo yẹ ki awọn ọmọ Naijiria ti wọn n gbe l'awọn orileede bii United Kingdom, USA, Canada, Ireland ati bẹẹ bẹẹ lọ ronu ree lati dokoowo lori dukia.
Gbajugbaja oniṣowo ile ati dukia naa lo sọrọ yii nibi ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe laipẹ yii, to si ni o ṣe pataki lati fi owo de nnkan, paapaa dukia mọlẹ.
Bakan naa lo sọ pe ki wọn wa jẹ anfaani ti ileeṣẹ Pelican Valley Nigeria Limited gbe kalẹ fun awọn ọmọ Naijiria ti wọn ti rin irin ajo tipẹ, ki wọn le ri nnkan gidi de ba, bi wọn ba pada de.
“O dara fun awọn eeyan lati dokoowo bayii, paapaa awọn ọmọ Naijiria ti wọn n gbe niluu Oyinbo. Wọn wa ni asiko anfaani to jọju bayii, nitori pe owo Dọla to lọ soke si Naira jẹ ohun ti wọn le fi ri nnkan gidi ṣe.
"Yoo tun mu ere nla gidi wa fun wọn bi wọn ba le fi owo dokoowo. Nitori naa, anfaani gidi ree lati ko owo sori ile gbigbe bayii.”
Adeyẹmọ, ẹni to ṣẹṣẹ gba oye Ambasadọ fun awọn ọdọ ilẹ adulawo, iyẹn ECOWAS Youth Ambassador ati Ambasadọ lori igbogunti iwa ajẹbanu ti a mọ si Anti-Corruption Ambassador ni lara awọn ojuṣe wọn ni lati ṣafihan awọn anfaani ti wọn ni nilẹ fawọn onibaara.
Lọjọ keji, oṣu kejila, ọdun 2023 ni Ọmọwe Adeyẹmọ yoo wa nibi ipade kan niluu London, eyi ti wọn pe ni London AVI Networking Event 2023, nibi ti wọn yoo ti maa sọrọ nipa dukia, ati bi wọn ṣe n ṣabojuto dukia lorileede Naijiria.
Ileeṣẹ kan ti wọn pe ni Avenue Impact Training & Consulting Limited, eyi to n ran awọn eeyan lọwọ nipa iṣẹ ti wọn le ṣe lo ṣagbekale eto ọhun, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
Siwaju sii ni Ọmọwe Adeyẹmọ jẹ ka mọ pe ileeṣẹ Pelican Valley Nigeria Limited yoo mu anfaani to pọ wọ ipinlẹ Ogun, eyi ti ko din ni miliọnu kan Euro nipasẹ didokoowo lori dukia.
No comments:
Post a Comment