Amechi fipa ja ibale ọmọ ọdun mẹrindinlogun n'Ikorodu, lo ba n sọ katikati niwaju adajọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, September 2, 2023

Amechi fipa ja ibale ọmọ ọdun mẹrindinlogun n'Ikorodu, lo ba n sọ katikati niwaju adajọ


Ọrọ burulu toun tẹrin nile ẹjọ Majisireeti to wa niluu Ikorodu, ipinlẹ Ekoo l'Ọjọbọ tii ṣe Tọside to kọja yii, nigba ti gendekunrin ọmọ ọdun mẹtalelogun kan ti ko niṣẹ lapa, Chibueze An Ikorodu n sọ katikati niwaju adajọ.
 
Ẹsun ifipabanilopọ ni wọn fi kan Amechi niwaju Onidajọ A.B. Ọlagbegi-Adelabu, ọmọ ọdun mẹrindinlogun kan ti a fi orukọ bo laṣiri ni wọn sọ pe Amechi fipa ja ibalẹ rẹ ni nnkan bi aago mẹfa irọlẹ, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu keje, ọdun 2023 ti a wa yii.
 
Agbegbe kan ti wọn n pe ni Evergreen Road, Ararọmi ni Imọta, Ikorodu ni wọn sọ pe iṣẹlẹ ọhun ti waye.
 
Gẹgẹ bi agbefọba Ọlawunmi Ọṣibanjọ to fẹsun meji ọtọọtọ to nii ṣe pẹlu ijinigbe ati ifipabanilopọ kan Amechi, o ni niṣe ni ọmọkunrin naa ji ọmọdebinrin ọhun gbe ni akata awọnn obi rẹ, to si lọ ọ fipa gba aṣọ iyi lara rẹ.
 
Oṣu kan gbako ni wọn sọ pe Amechi fi gbe ọmọdebinrin naa pamọ sinu ile, to si n ko ibasun fun un karakara, ko to di pe aṣiri rẹ tu sita.
 
Ẹsun yii ni Ọṣibanjọ sọ pe o tako iwe ofin ọdaran ipinlẹ Ekoo t'ọdun 2015 ni abala 269 ati 137.
 
Nigba to n sọrọ, Onidaọ Ọlagbegi-Adelabu, to kọ lati gbọ ẹbẹ ati awijare Amechi paṣẹ pe ko ṣi lọ farapamọ si ọgba ẹwọn Kirikiri titi digba ti igbẹjọ yoo fi waye lọjọ kejila, oṣu kẹwaa, ọdun yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI