Alaga ẹgbẹ awọn gomina lorileede Naijiria, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq, ẹni to tun jẹ gomina ipinlẹ Kwara ti ba aarẹ orileede yii, Bọla Ahmẹd Tinubu yọ lori bo ṣe jawe olubori nile ẹjọ to tako eto idibo ọdun 2023 to kọja lọ.
Gomina AbdulRazaq sọ pe aridaju ododo to foju han ni idajọ naa jẹ, to si l'awọn adajọ naa ko f'igba kan bo ẹjọ naa ninu, ati pe wọn ṣe e nilana to ba ofin mu.
O ni idajọ naa jẹ eyi to fi ontẹ lu idibo to gbe Aarẹ Tinubu wọle s'ipo, ati pe o jẹ eyi to fi ifẹ awọn araalu han lori bi wọn ṣe dibo yan Aarẹ Tinubu.
No comments:
Post a Comment