Ijọba ipinlẹ Kwara laipẹ yii ti tọwọ bọwe adehun pẹlu ajọ ijọba, National Agriculture Land Development Authority (NALDA) lati ni ajọṣepọ to dan mọnran, lori eto ounjẹ jijẹ, paapaa lojuna lati jẹ ki ounjẹ pọ lọpọ yanturu.
Kọmiṣanna fọrọ eto agbẹ ati ọgbin ati idagbasoke awọn agbegbe, Arabinirin Ọlọruntoyọsi Thomas lo sọ eyi di mimọ laipẹ yii lakoko to n ṣabojuto agbegbe ti ya sọtọ fun gbigbin ire oko ti yoo mu adinku ba iṣoro ounjẹ.
Agbegbe ti wọn ya sọtọ yii lo wa niluu Malete, ijọba ibilẹ Moro, gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ti wọn si ni yoo jẹ ki eto aabo wa lori awọn ounjẹ ipinlẹ naa.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni lati le mu ẹdinku ba iṣoro ti awọn eeyan, paapaa awọn agbẹ yoo koju lasiko ọgbẹ-ilẹ, ijọba ti pa a laṣẹ fun ileeṣẹ to n ri sọrọ eto agbẹ lati ṣagbekalẹ eto ọgbin lasiko ọgbẹ-ilẹ, lojuna lati ni anfaani si ounjẹ ti yoo ṣee kowo le lori, ti yoo si mu adinku ba iṣoro ounjẹ.
Nibẹ lo tun ti jẹ ko di mimọ pe tun ti gbe eto miran kalẹ f'awọn ọdọ ilu Malete, eyi to pe ni Malete Integrated Youth Farm Training Centre, ti yoo jẹ k'awọn ọdọ ni anfaani si ṣiṣe iṣẹ agbẹ.
No comments:
Post a Comment