Ara ko r'okun, bẹẹ ni ara ko ro adiẹ fun awọn ara agbegbe Adunbun to wa niluu Itori, ijọba ibilẹ Ewekoro, ipinlẹ Ogun pẹlu bi wọn ṣe sọ pe gbajugbaja oniṣowo ilẹ kan, Oloye Mutairu Owoẹyẹ ko awọn tọọgi wọ agbegbe naa lati dunkooko mọ awọn eeyan.
Laipẹ yii ni iroyin tẹ wa lọwọ pe Oloye Owoẹyẹ ran awọn tọọgi si Oloye Kayọde Falọla, ẹni to jẹ Baalẹ agbegbe Adunbun, ti wọn si luu lalubami.
Kii ṣe akọkọ ree ti awọn eeyan yoo maa fẹsun kan Oloye Owoẹyẹ, paapaa lori ọrọ ajagungbalẹ n'ipinlẹ Ogun.
A gbọ pe iṣakuṣa ni wọn ṣa Falọla, pẹlu erongba lati gb'ẹmi rẹ, ṣugbọn ti ori pada ko o yọ lọwọ iku ojiji, to si wa l'ọsibitu nibi to ti n gba itọju titi di asiko ti a wa yii.
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe awọn ara agbegbe Adunbun ko le sun, ki wọn si di oju mejeeji mọ bayii, pẹlu bi wọn ṣe sọ pe ojoojumọ l'awọn ajagungbalẹ ti Owoẹyẹ n lo lati maa fi ṣiṣẹ yii n da wọn laamu.
Bi wọn ṣe n wọ agbegbe naa lọganjọ oru, bẹẹ ni wọn n fi ọsan gangan ati aarọ kutu wọle lati dunkoko mọ awọn araalu.
Ninu iroyin to tẹ wa lọwọ, wọn sọ pe gendekunrin kan, Mọjeede Ẹnitinwa to ṣẹṣẹ de lati ọgba ẹwọn ni olori awọn tọọgi ti Owoẹyẹ n lo lati maa fi dunkooko mọ awọn eeyan.
Wahala ati idaamu t'awọn ara agbegbe naa n koju lo jẹ ki wọn kọ iwe ẹsun, ti wọn si fi ranṣẹ si ọga ọlọpaa pata lorileede Naijiria, ti wọn si sọ pe awọn ọlọpaa lọ gbe Mọjeed Enitinwa lati fọrọ wa a lẹnu wo.
Ibinu wi pe ọlọpaa gbe Mọjeed, lo mu k'awọn ọmọ ẹyin rẹ faraya, ti wọn si lọ kọlu gbogbo awọn to lọwọ si lẹta ifẹsunkan naa, koda ti wọn sọ pe aludojubolẹ ni wọn lu Ṣhobakin Akanji, ẹni to jẹ olori ẹbi Adunbun.
Lara awọn to ba oniroyin sọrọ, awọn ti wọn ni ka fi orukọ bo awọn laṣiri nitori aabo ṣalaye pe ọganjọ oru, ni nnkan bi aago kan ni awọn tọọgi ajagungbalẹ ti ko din ni ọgbọn ya wọ agbegbe Adunbun, ti wọn si lu Falọla lalubami.
Wọn l'awọn ajagungbalẹ naa lọ sile Falọla to jẹ Baalẹ ilu naa lati gb'emi rẹ. Lẹyin ti wọn lu tan ni wọn fi okun de e, ti wọn si lọ juu danu sinu igbo kan to jinna si ile rẹ. Lẹyin eyi ni wọn dana sun ile rẹ, ti wọn si tun run mọto rẹ womuwomu.
Awọn alaanu to n kọja lọ la gbọ pe wọn ri i, ti wọn si sare gbe e lọ si ọsibitu fun itọju, ibẹ si lo wa titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii tan. Koda, wọn ni Falọla ko tii le sọ boya aye loun ṣi wa tabi ọrun.
Bi wahala naa ṣe n fojoojumọ ṣẹlẹ ni wọn sọ pe o mu k'awọn kan ko ẹru kuro niluu lati lọ maa gbe niluu to tun sunmọ wọn, iyẹn lati sa asala fun ẹmi ara wọn.
Wọn l'awọn ti lọ fi to Olu Itori, Ọba Abdulfatai Akorede Akamọ leti, ṣugbọn ti kabiyesi naa ko ri nnkan ṣe si i titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii.
Eyi lo wa fa a, ti wọn fi n rawọ ẹbẹ si ijọba ipinlẹ Ogun labẹ Gomina Dapọ Abiọdun, ijọba apapọ ati gbogbo awọn oṣiṣẹ eleto aabo patapata lati ran wọn lọwọ lori ọrọ yii.
Bakan naa ni wọn tun n rawọ si ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun, to fi mọ ọga ọlọpaa patapata lorileede Naijiria lati dide iranlọwọ fun wọn, ki alaafia le pada siluu Adunbun naa.
Gbogbo akitiyan lati ba Oloye Mutairu Owoẹyẹ sọrọ lori iṣẹlẹ yii lo ja si pabo titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, ti a si nigbagbọ wi pe a ṣi maa pada gbọ t'ẹnu rẹ.
A ṣeleri wi pe ohunkohun ti Oloye Owoẹyẹ ba sọ la maa gbe jade fun un yin laipẹ.
No comments:
Post a Comment