Gomina Abdulrahman Abdulrazaq ti ipinlẹ Kwara ti gbe oku aṣoju Naijiria si orileede France, Oloogbe Latinwọ Laro wọle siluu Ilọrin, ipinlẹ naa.
AbdulRazaq ati awọn alẹnulọrọ n'ipinlẹ naa ni wọn lọ pade awọn to lọ gbe oku naa wa sile, iyẹn laarọ Ọjọru tii ṣe Wesidee ana.
Bi wọn ṣe gba oku naa, la gbọ pe eto isinku bẹrẹ ni ilana musulumi loju ẹsẹ, ti wọn ko si fi akoko ṣofo
Papakọ ofurufu tiluu Tunde Idiagbon to wa n'Ilọrin ni Gomina AbdulRazaq ti lọ pade oku naa, nigba ti ọkọ baluu awọn ọmọ ogun Nigeria Air Force gbe e de pẹlu aami idanimọ Naijiria
Yatọ si gomina ati awọn alẹnulọrọ ni Kwara, awọn mọlẹbi oloogbe naa ko gbẹyin nibi ti wọn ti lọ pade oku na.
Eto isinku naa ni Imaamu agba niluu Ilọrin, Sheikh Mohammed Bashir Soliu ṣakoso rẹ.
No comments:
Post a Comment