Tinubu at'awọn gomina Naijiria mẹfa wọ ilẹ olominira Bẹnin lonii fun ayẹyẹ ọjọ igbominira - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, August 1, 2023

Tinubu at'awọn gomina Naijiria mẹfa wọ ilẹ olominira Bẹnin lonii fun ayẹyẹ ọjọ igbominira


Aarẹ orileede Naijiria, Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu ati awọn gomina ipinlẹ mẹfa ni iroyin ti fi to wa leti pe wọn ti wa lorileede olominira Bẹnin lati ba wọn ṣayẹyẹ ayajọ ọjọ igbominira wọn.
 
Lara awọn gomina naa ni alaga ẹgbẹ awọn gomina ni Naijiria, AbdulRahman AbdulRazaq t'ipinlẹ Kwara; Gomina Babajide Sanwo-Olu t'ipinlẹ Ekoo;   Gomina Ṣeyi Makinde t'ipinlẹ Ọyọ; Gomina Dapọ Abiọdun t'ipinlẹ Ogun; Gomina Nasir Idris t'ipinlẹ Kẹbbi, to fi mọ Gomina Mohammed Bago t'ipinlẹ Niger.

Gẹgẹ bi a sẹ gbọ, ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun mẹtalelọgọta ni ilẹ olominira Bẹnin n ṣe lonii, ọjọ kinni, oṣu kẹjọ, ọdun 2023.
 
Aarẹ ilẹ olominira Bẹnin, Patrice Talon lo fi iwe ipe alejo pataki ranṣẹ si Aarẹ Tinubu, toun naa si ko ikọ akọwọrin rẹ lẹyin, gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ awọn aarẹ nilẹ adulawọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI