Gbogbo eto lo ti pari bayii fun gbajugbaja onkọrin nni, Ọmọtoyọsi Kayọde Iyun Ajilore, ẹni ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si St Janet lati dalu bolẹ niluu Abẹokuta tii ṣe olu-ilu ipinlẹ Ogun.
Opin ọsẹ ti a wa yii, ọjọ Abamẹta tii ṣe Satide, ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹjọ, ọdun 2023 ti a wa yii ni Saint Janet yoo wọ ilu Abẹokuta lati fi orin, ilu ati ijo da awọn ololufẹ rẹ laraya.
Ẹgbẹ awọn akẹkọọjade, iyẹn Old Students Association ti ile-ẹkọ girama Anglican High School to wa lagbegbe Ibara niluu Abẹokuta ni wọn pe Saint Janet lati wa a fi orin da wọn laraya.
Awọn akẹkọọjade naa ni saa ikẹkọọ ọdun 1995 si 1996 ni iroyin fi to wa leti wọn fẹẹ ṣayẹyẹ eto ipade ọlọdọọdun (Annual General Meeting) wọn lọjọ naa, bẹrẹ lati deedee agogo mẹwaa owurọ.
Nigba to n sọrọ, Aarẹ ẹgbẹ awọn akẹkọọjade naa, Oloye Arẹmu Oyedele Bamgboye, ẹni ti ọpọ awọn eeyan tun mọ si Ajiki-Olu jẹ ko ye wa pe lọdọọdun l'awọn maa n ṣe ohun ara ọtọ, to si ni tọdun yii yoo tun ju awọn eyi to ti kọja lọ.
O ni lara awọn pataki idi t'awọn fi fẹẹ gbe Saint Janet, ti wọn tun n pe ni Mama Yabis wa ni pe orin rẹ maa n da awọn eeyan laraya gidigid, kii sii ṣe olorin ti yoo maa kọrin, t'awọn eeyan yoo maa sun lori ijokoo.
Ajiki-Olu fi ye wa pe inu ọgba ile-ẹkọ naa ni ipade ọhun yoo ti waye, bo tilẹ jẹ oun ko tii le sọ igba ti ipade naa yoo pari.
O fi kun ọrọ re pe eto aabo wa fun awọn alejo wọn, paapaa awọn alejo pataki ti wọn fi iwe pe lati darapọ mọ wọn.
Bakan naa lo fi kun un pe awọn ọga ile-ẹkọ mejeeji ni yoo wa nibẹ lọjọ naa.
No comments:
Post a Comment