Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekoo ti sọ pe awọn ko nii fi ọwọ yẹpẹrẹ mu iwa ilọnilọwọgba, jibiti ati riba to n ṣẹlẹ kaakiri ipinlẹ naa mọ, paapaa eyi ti awọn aṣoju wọn n ṣe kaakiri lati maa fi doju ti wọn.
Ọga ọlọpaa ipinlẹ naa, Idowu Ọmọhunwa lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade ti alukoro ọlọpaa, Benjamin Hundẹyin gbe sita lọjọ Abamẹta tii ṣe Satide to kọja yii.
Nibẹ lo ti jẹ ko di mimọ pe ọwọ awọn ti tẹ ọlọpaa mẹta, oṣiṣẹ ajọ ẹṣo oju popona t'ijọba apapọ, FRSC kan, oṣiṣẹ ẹṣọ oju popona t'ipinlẹ Ekoo kan, to fi mọ awọn tọọgi ti ko din ni mẹẹdogun lọwọ awọn ti tẹ bayii.
Hundẹyin sọ pe ẹsun ilọnilọwọgba ni wọn fi kan gbogbo wọn, ti wọn si n jaye familete-ki-n-tutọ kaakiri ipinlẹ naa.
O sọ pe oriṣiriṣi iwe ẹsun l'awọn ti gba lati ọdọ awọn to n wa mọto, paapaa awọn oni tirela nla wi pe awọn ọlọpaa FRSC, LASTMA ati awọn tọọgi maa n da wọn duro lati gba owo aitọ lọwọ awọn.
Hundẹyin ni wọn sọ pe awọn owo ti awọn eeyan naa n gba lọwọ awọn ni ko ni akọsilẹ, lẹyin ti wọn ba ti gba awọn iwe to ba yẹ, eyi ti wọn sọ pe ko bojumu to.
Eyi lo fa a ti ọga ọlọpaa fi gbe igbimọ oluwadii dide, ti igbakeji ọga ọlọpaa ipinlẹ naa lẹka amuṣeya si lewaju igbimọ naa, lati ṣe iwadii lẹkunrẹrẹ.
O jẹ iyalẹnu wi pe ọjọ akọkọ ti igbimọ naa yoo jade sita lati ṣiṣẹ wọn ni ọwọ tẹ ọlọpaa mẹta, oṣiṣẹ FRSC kan, oṣiṣẹ LASTMA kan ati awọn tọọgi mẹẹdogun.
Agbegbe Mile 2 to wa nipinlẹ naa la gbọ pe ọwọ palaba gbogbo ti segi, koda, ibẹ gan-an ni wọn pe ni olu ileeṣẹ awọn alọnilọwọgba kaakiri ipinlẹ Ekoo.
Ọga Ọlọpaa naa, Ọmọhunwa ti wa a ṣe ikilọ sita fun gbogbo awọn agbofinro patapata lai yọ ẹka kankan silẹ lati ki ọwọ ọmọ wọn bọ aṣọ nitori pe ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ lori iwa adojutini naa yoo foju winna ofin.
Bẹẹ lo f'ọkan awọn araalu balẹ, pẹlu ileri wi pe igbimọ naa yoo maa ṣiṣẹ kaakiri ipinlẹ naa, lati ri i pe iwa ọhun d'opin patapata, ti iwa ọmọluabi yoo si pada saarin ilu.
No comments:
Post a Comment