Niṣe ni idunnu ṣubu lu ayọ ọga agba patapata n’ileeṣẹ tẹlifiṣan ijọba apapọ, Nigeria Telivision Authority {NTA}, Oloye Arabinrin Funmilayọ Wakama nigba to fẹyinti lẹnu iṣẹ, to si tun di oloye tuntun niluu Owu, Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.
Ọjọ Abamẹta tii ṣe Satide, ọsẹ to kọja yii ni ayẹyẹ onibeji naa waye niluu Abẹokuta, ti obinrin naa to ti ko ipa ribiribi nidi iṣẹ iroyin ati igbohunsafẹfẹ lorileede Naijiria.
Wakama, ẹni to ti f’igba kan ri jẹ akọwe iroyin gomina ipinlẹ Ogun labẹ iṣakoso Sẹnetọ Ibikunle Amosun lo n fi ẹmi imoore han si Ọlọrun, to si loun ko le ṣai dupẹ gidigidi lọwọ ọkọ oun to faaye silẹ foun lati ṣiṣẹ.
Nibi eto naa ni Olowu tiluu Owu, Ọba Ọjọgbọn Saka Matẹmilọla fi oye Yeye Fiwagboye tiluu Owu da obinrin naa lọla, ati ọkọ rẹ toun naa joye Fiwagboye tiluu Owu, Abẹokuta.
Nigba to n sọrọ, Wakama sọ pe idunnu nla lo jẹ foun lati fẹyin gẹgẹ bi oṣiṣẹ ijọba ni ipele kẹtadinlogun, toun si tun ṣi ni agbara lati ṣiṣẹ miran siwaju sii.
Bakan naa lo kede ileeṣẹ tuntun tiẹ to pe ni Allround Communications Company, pẹlu ileri wi pe ajọ alaanu Funmi Wakama toun da silẹ ko nii dawọ duro, to si ni mejeeji yoo maa ṣiṣẹ papọ.
Gomina tẹlẹri nipinlẹ Ogun, Oloye Oluṣẹgun Ọṣọba ṣapejuwe Wakama gẹgẹ bi akikanju obinrin to duro ṣinṣin, to si ṣee fọkan tan, paapaa nidi iṣẹ iroyin ati igbohunsafẹfẹ.
Ọba Matẹmilọla ninu ọrọ tiẹ naa sọ pe ipa rere ti Wakama ati ọkọ rẹ n hu lawujọ lo fa a ti wọn fi lẹtọọ si oye naa, to si gba wọn lamọran lati tẹsiwaju.
No comments:
Post a Comment