Ọdun Iṣẹṣe: Gomina Dapọ Abiọdun kede ọjọ Aje, Mọnde gẹgẹ bi ọlude - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, August 21, 2023

Ọdun Iṣẹṣe: Gomina Dapọ Abiọdun kede ọjọ Aje, Mọnde gẹgẹ bi ọlude



Gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun ti kede ọjọ Aje tii ṣe Mọnde gẹgẹ bi ọjọ ọlude fun gbogbo awọn araalu lati fi saami ayẹyẹ ayajọ ọdun iṣẹṣe.

Ọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii ni Gomina Abiọdun sọ pe ọjọ Mọnde naa, iyẹn ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹjọ, ọdun ti a wa yii bi ọjọ isinmi fun gbogbo awọn oniṣẹṣe patapata.

Ṣaaju asiko yii ni gbogbo awọn oniṣẹṣe patapata lorileede Naijiria, paapaa nilẹ Yoruba ti n pe fun ogunjọ, oṣu kẹjọ, ọdọọdun gẹgẹ bi ọjọ ti wọn yoo maa ṣe ọdun iṣẹṣe, eyi ti wọn ti ya sọtọ tipẹtipẹ.

Ninu atẹjade ti akọwe iroyin gomina, Ọgbẹni Lekan Adeniran fi sita, Abiọdun gbe oriyin fun gbogbo awọn oniṣẹṣe patapata n'ipinlẹ Ogun fun ifọwọsowọpọ wọn, ati bi wọn ṣe ṣe ara wọn ni oṣuṣu-ọwọ.

O ni ipinnu naa ni lati bu ọwọ to tọ fun ẹsin abalaye ati mimu ki ibaṣepọ to dan mọnran wa laaarin awọn ẹlẹsin mẹtẹẹta to wa ni ipinlẹ naa.

Bakan naa ni Gomina Abiọdun tun fi erongba rẹ han si gbigbaruku ti ati bibu ọla fun gbogbo ẹsin patapata to wa ni ipinlẹ naa.

Siwaju sii lo parọwa si gbogbo awọn ẹlẹsin iṣẹṣe naa lati ṣajọyọ naa ni irọwọ-irọsẹ, ki wọn si yago fun awọn iwa to le da alaafia ipinlẹ naa laamu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI