Ẹsẹ ko gbero niluu Abẹokuta l'ọjọ kẹjọ, oṣu kẹjọ, ọdun 2023 ti a wa yii nigba ti gbajugbaja sorọsọrọ agbaye nni, Kọlawọle Atanda Adejojo se ẹwa ibeji fun awọn ibeji ti ko din ni ọgọrun-un, lati fi mu inu wọn dun.
Kii ṣe pe Kọlawọle Adejojo, ẹni ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ tun mọ si Kasnaty se ẹwa ibeji nikan, o tun ro ọpọ awọn alaini, paapaa awọn opo lagbara nipa fifun wọn ni owo lati fi bẹrẹ okoowo ti wọn ba fẹ.
Agboole kan ti wọn n pe ni Agbebeji-Gun-Ori-Ẹṣin, ni adugbo Agọ-Ika, ijọba ibilẹ Abẹokuta North, Abẹokuta, ipinlẹ Ogun ni eto ọhun ti waye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, Kasnaty ni wọn loo ronu lati ṣe nnkan to da yatọ si awọn eyi to ti n ṣe tẹlẹ, nitori naa lo ṣe gbe eto ọhun kalẹ lati mu ori awọn ibeji wu.
Nigba to sọrọ, ọkan lara awọn ibeji nibi eto naa sọ pe idunnu lo jẹ f'oun nitori pe oun ko tii ri iru nnkan bẹẹ ri latigba toun ti d'aye, to si lo jọ oun loju pupọ.
Ọgbẹni Akeem Idowu to jẹ olori ẹbi Agbebeji-Gun-Ori-Ẹṣin ninu ọrọ rẹ ṣalaye pe awọn iya to bi awọn baba wọn bi ibeji pupọ, to si loun naa tọ ipasẹ wọn nipa bibi ibeji lẹẹmeji ọtọọtọ.
Idowu ni "Nigba ti wọn pe mi pe Kasnaty fẹẹ gbe eto kalẹ f'awọn ibeji, paapaa ni agboole wa ti mo jẹ olori ẹbi nibẹ, mi o kọkọ mọ ohun ti wọn n sọ, ṣugbọn nigba ti ipalẹmọ naa bẹrẹ, inu mi bẹrẹ sii dun wi pe igba ọtun ti de.
"A ko ṣe iru nnkan bayii ri latigba ti mo ti de ile aye, mo si nigbagbọ pe ọdọọdun la ma maa ṣe e nitori pe mo ti n ri anfaani ninu ẹ.
"Idi ti wọn ṣe n pe agboole wa ni Agbebeji-Gun-Ori-Ẹṣin ni pe nigba awọn baba nla wa. Wọn bi ibeji to pọ, wọn si ni ẹṣin ti wọn n gun. Bi wọn ba fẹẹ lọ s'oko, ori ẹṣin yii ni wọn maa gbe awọn ibeji si, ti wọn si jọ maa lọ.
"Eyi ti n ṣẹlẹ tipẹ ko to di pe awọn eeyan bẹrẹ sii pe awọn ni Agbebeji-Gun-Ori-Ẹṣin, nitori to jọ awọn eeyan igba naa loju. Lara eewọ idile wa si ni pe ẹnikẹni ko gbọdọ gbe ibeji lọ tọrọ baara kaakiri igboro, ajalu buruku lo maa jẹ."
Lakotan, o dupẹ lọwọ Kasnaty fun ipa to n ko lawujọ awọn agbohunsafẹfẹ, nitori pe oun gan-an lo n gbe eto igbohunsafẹfẹ lọ ba awọn eeyan nile wọn lati mọ bo ṣe n ri.
Kasnaty ninu ọrọ tiẹ naa sọ pe "Ibeji to n jẹ anfaani nibi lonii to ọgọrun-un kan. Mo kan wo o pe ki n tun ṣe nnkan to da yatọ. Nibi ti mo ti n ṣeto kaakiri ni mo ti ṣalabapade agboole yii, o si ya mi lẹnu pupọ.
"Mo wa ronu pe ki ni mo tun le ṣe to le da yatọ, idi ree ti mo fi wo o pe ki n ṣayẹyẹ f'awọn ibeji. Mo tun lọ gbe ẹṣin wa, ki ayẹyẹ naa lẹ tun ni itumọ. Bi mo ṣe n ṣeto kaakiri naa ni mo tun n ri ẹkọ kọ.
"Iro lagbara wa ninu eto ti mo n ṣe kaakiri, bẹẹ ni mo tun n kọ awọn eeyan lẹkọọ. A ti fi eto yii wa iṣẹ f'awọn eeyan, bẹẹ l'awọn miran ti bẹrẹ okoowo ti wọn ko lero tẹlẹ.
"Nibi lonii, awọn eeyan gba owo to ṣee dokoowo, bẹẹ ni wọn tun jẹun. Idaji miliọnu naira la fi se ẹwa ibeji. Ọlọrun lo n ran mi lọwọ lori eto yii kii ṣe eniyan.
"Ẹnikan to n tọrọ baara tẹlẹ ti ri aanu gba lori eto ti mo n gbe kaakiri, o si ti bẹrẹ sii ta ọja bayii.
"Lara awọn erongba wa tun ni pe bi awọn akẹkọọ ba fẹẹ wọle pada bayii, a maa bẹrẹ sii pin baagi fun wọn. A ti ri awọn ti wọn n ran lọ sileewe nipaṣe eto yii."
O wa rọ awọn eeyan lati ṣamulo iru igbesẹ tiẹ yii lati le din iṣẹ ati oṣi ku lawujọ.
No comments:
Post a Comment