Ijọba Kwara tun bẹrẹ sii pin owo iranwọ f'awọn ọlọja - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, August 17, 2023

Ijọba Kwara tun bẹrẹ sii pin owo iranwọ f'awọn ọlọja


Ijọba ipinlẹ Kwara ti kede sita pe awọn ti eto pinpin owo iranwọ ti awọn oloyinbo n pe ni Palliatives fun awọn ọlọja kaakiri ipinlẹ naa, lati le mu idẹrun ba wọn lakoko rogbodiyan ọwọngogo to wa nita yii.

Yatọ si awọn ọlọja yii, awọn oniṣẹ ọwọ ati olokoowo kekeeke naa ni wọn tun n jẹ anfaani yii lati le jẹ ki eto ọrọ aje lọ soke n'ipinlẹ ọhun.

Ileeṣẹ ijọba ti wọn pe ni Kwara State Social Investment Programme (KWASSIP), la gbọ oe wọn n ṣagbatẹru pinpin owo iranwọ naa fawọn araalu, to fi mọ awọn to ku diẹ kaato fun.
 
Awọn ọlọja ati olokoowo kekeeke to le diẹ ni ẹgbẹrun kan aabọ (1,551), ti wọn ti tete fi orukọ silẹ ni iroyin fi to wa l'eti pe wọn jẹ anfaani yii ni ipele yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI