Ijọba ipinlẹ Kwara laipẹ yii ti fi awọn irinṣẹ ayẹwo ilera igbalode ta ọsibitu ijọba to wa niluu Ọffa, ipinlẹ naa lọrẹ, lojuna lati jẹ k'awọn araalu máa jẹ mudunmudun eto ilera igbalode.
Yatọ si eyi, ijọba nnaa tun yan awọn akọṣẹmọṣẹ dokita ati nọọsi s'awọn ọsibitu kaakiri lati le jẹ ki awọn araalu maa jẹ igbadun eto ilera lọna to yọranti.
Awọn irinṣẹ ayẹwo ilera igbalode yii ni wọn yoo wa ninu yara itọju, iyẹn laboratory, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe awọn alakoso ọsibitu n'ipinlẹ naa, Kwara State Hospital Management Board (KW-HMB).
Lara awọn irinṣẹ ayẹwo igbalode naa ni wọn pe ni Hematology Analyzer, Hormonal Profile Analyzer ati Electrolyte Analyzer.
Nigba to n sọrọ, alakoso KW-HMB, Dọkita Abdulraheem Malik sọ pe gbogbo awọn oṣiṣẹ eleto ilera ti wọn yoo lo awọn irinṣẹ wọnyi ni wọn ti la idanilẹkọọ bi wọn yoo ṣe lo o kọja.
Bẹẹ lo sọ pe awọn alaisan ko nilo lati maa rin irin ajo lọ siluu Ilọrin mọ lati gba itọju, nitori pe ohun ti wọn n wa lọ ṣokoto ti wa l'apo ṣokoto wọn.
O fi kun ọrọ rẹ pe awọn yoo tubọ maa ko awọn irinṣẹ ilera igbalode lọ s'awọn ọsibitu kaakiri, fun irọrun araalu.
No comments:
Post a Comment