Lati le mu ẹdinku ba ijamba ori omi, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara l'Ọjọbọ tii ṣe tọsidee to kọja yii ti fi aṣọ aabo ori omi ti ko din ni ẹgbẹrun kan ta awọn araalu Patigi lọrẹ, eyi ti yoo maa daabo bo awọn eeyan bi wọn ba n rin irin ajo ori omi.
Bẹ o ba gbagbe, ni nnkan bi ọsẹ meloo kan sẹyin ni ijamba ori omi waye miluu Patigi, to si fi ọpọ ẹmi to le ni ọgọrun-un kan ṣofo danu.
Latigba naa ni ijọba Kwara ti ṣe ileri wi pe gbogbo ohun ti yoo ba gba l'awọn yoo fun un lati rii pe iru ijamba bẹẹ ko tun waye mọ, ati pe loore-koore l'ohun yoo maa ṣe iranwọ lori eto ti yoo dẹkun ijamba ori omi.
Nigba to n fa awọn aṣọ aabo (Life Jackets) naa le Etsu tiluu Patigi, Alaaji Umar Bologi keji lọwọ, iyẹn to ti kọkọ b'awọn ọba alaye ṣepade, nibi ti wọn ti ṣalaye eto aabo ati igbayegbadun araalu fun un, Gomina sọ pe eto aabo ati alaafia araalu jẹ oun logun pupọ, toun si gbọdọ maa ṣe awọn nnkan to yẹ fun igbayegbadun wọn.
Bakan naa ni gomina sọ pe iru nnkan bayii yoo tun ṣẹlẹ laipe n'ijọba ibilẹ Edu ati awọn agbegbe miran ti wọn ti n fi omi ṣe ọrọ aje wọn, lati le rii daju pe igbokegbodoo ọkọ oju omi n lọ bo ti tọ ati bo ti yẹ.
Lara awọn to wa nibi eto ọhun ni alaga ẹgbẹ awọn ijọba ibilẹ nipinlẹ Kwara, Ọnarebu Jide Asonibare; alaga igbimọ ẹgbẹ awọn ọba alaye ni Kwara, Etsu Patigi, Alaaji Umar Bologi II; Ọlọfa tiluu Ọffa, Ọba Mufutau Gbadamọsi Eṣuwoye; Olupo tiluu Ajaṣẹ-Ipo, Ọba Ismaila Yahaya Alebioṣu; Emir tiluu Kaiama, Alaaji Muazu Shehu Omar; ati Olomu tiluu Omu Aran, Ọba AbdulRaheem Ọladele Adeoti.
No comments:
Post a Comment