Gbogbo araalu lo maa jẹ anfaani eto iranwọ ti ijọba apapọ fi ranṣẹ si Kwara - Gomina AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, August 24, 2023

Gbogbo araalu lo maa jẹ anfaani eto iranwọ ti ijọba apapọ fi ranṣẹ si Kwara - Gomina AbdulRazaq


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti ṣe ileri nita gbangba wi pe gbogbo ara, ọmọ ati olugbe ipinlẹ naa ni yoo jẹ ninu anfaani iranwọ (Palliatives) oni biliọnu marun-un ti ijọba apapọ fi ranṣẹ si wọn.
 
Gomina Abdulrazaq lakoko to n jẹri si gbigba iwe sọwedowo oni biliọnu meji naira tijọba apapọ fi ranṣẹ si wọn ninu biliọnu marun-un naira ti ipinlẹ kọọkan yoo gba gẹgẹ bi ohun iranwọ lati mu idẹrun ba ọwọngogo ti owo iranwọ ori epo ti wọn yọ kuro fa, o ni gbogbo araalu lo gbọdọ jẹ anfaani naa.
 
O ni gbogbo awọn araalu pata, paapaa awọn mẹkunnu ni yoo gba irẹsi, iree oko bii agbado eyi ti ijọba apapọ fi ranṣẹ si wọ lai fi ti ọrọ oṣelu ṣe.
 
Siwaju sii ni gomina sọ pe awọn nilo lati maa jẹ k'araalu mọ bo ṣe n lọ, nitori pe awọn ko le fi igba kan bo ọkan ninu fun wọn, nitori pe ẹtọ wọn ni, wọn si gbọdọ mọ bi nnkan ṣen lọ si.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI