Awọn alaṣẹ ati alakoso ileewe giga fasiti agbẹ ati ọgbin, Federal University of Agriculture (FUNAAB) to wa niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun ti sọ pe eto ayẹyẹ ikẹkọọgboye, ọgbọn ọdun iru ẹ yoo bẹrẹ ni pẹrẹu, bẹrẹ lati ọjọ kẹrin, oṣu kẹjọ, ọdun 2023.
Eto naa la gbọ pe yoo bẹrẹ pẹlu kiki irun Jummaati ninu mọṣalaṣi ileewe fasiti naa, bẹrẹ lati aago kan ọsan.
Ninu atẹjade ti alakoso eto igbaniwọle ni fasiti naa, Ọmọwe 'Bọla Adekọla buwọ lu, eyi ti ẹda rẹ tẹ AWIKONKO lọwọ, o ni wọn yoo tun ṣe isin ajumọṣe ninu ile ijọsin fasiti, eyi ti yoo bẹrẹ lati aago mẹsan aarọ.
Ọmọwe Adekọla sọ pe l'Ọjọbọ tii ṣe Tọsidee, ọjọ kẹwaa, oṣu kẹjọ, ọdun ti a wa yii ni ipade awọn akọroyin yoo waye lati fi ṣalaye ibi ti iṣẹ de duro ninu ileewe ọhun ni deedee aago mẹwaa aarọ.
Siwaju sii lo sọ pe lẹyin ipade awọn akọroyin, wọn yoo ṣi awọn akanṣe iṣẹ ti wọn ti ṣe ninu ọgba naa fun lilo laago mọkanla aarọ ọjọ naa.
Bẹẹ lo ni eto ayẹyẹ ọlọsẹ kan naa yoo larinrin pẹlu eto ọlọkan-o-jọkan ti wọn ti la kalẹ, nibi ti awọn akẹkọọ yoo ti kẹkọọ gboye, ti awọn Musulumi to si ṣe daadaa yoo gba aami ẹyẹ l'ọjọ Ẹti tii ṣe Furaide, ọjọ kọkanla, oṣu yii, iyẹn ninu gbọngan ayẹyẹ Olufẹmi Balogun, bẹrẹ lati aago mẹwaa aarọ.
O tun fi kun un pe idanilẹkọọ eto ayẹyẹ ikẹkọọgboye naa yoo waye lati ẹnu minisita tẹlẹri f'ọrọ eto ẹkọ lorileede Naijiria ati igbakeji Aarẹ Banki agbaye tẹlẹri, Ọmọwe Oby Ezekwesili.
Bẹẹ lo ni wọn yoo ṣe eto wẹjẹ-wẹmu fawọn alejo ọjọ naa ninu gbọngan International Scholars’ and Resource Centre (IS&RC), ni aago kan ọsan, lẹyin eyo naa.
No comments:
Post a Comment