Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti ṣapejuwe Adeṣina Shalom Ọlọlade gẹgẹ bi ọlọgbọn, akikanju ọmọdekunrin to ja fafa daadaa lẹnu ẹkọ rẹ, to si jẹ ọjọ iwaju rere fun ipinlẹ naa.
Ọlọlade jẹ akẹkọọ-kunrin to ṣe daadaa ninu idanwo aṣekagba nile ẹkọ girama, iyẹn West African Examination Council, WAEC to waye kọja lọ yii n'ipinlẹ naa.
A gbọ pe gbogbo iṣẹ mẹsẹẹsan ti Ọlọlade ṣe idanwo rẹ lo yanranti patapata lai ku eyọkan, aṣeyọri ti wọn sọ pe ko wọpọ lasiko yii.
Bakan naa la gbọ pe Ọlọlade tun gba 298 ninu idanwo aṣewọle sile ẹkọ giga, iyẹn Unified Tertiary Matriculation Examination (UTME), to kọja lọ, ti wọn si loun ni akẹkọọ to ṣe daadaa nipinlẹ naa.
Gomina sọ pe esi idanwo naa ti han bi Ọlọlade ṣe ṣiṣẹ takuntakun, pẹlu afojusun rere rẹ, paapaa nipa iranlọwọ awọn obi rẹ ti wọn gbauruku lati maa ka iwe rẹ loorekoore.
O wa gba awọn ọjẹwẹwẹ n'ipinlẹ naa lamọran lati gbajumọ eto ẹkọ wọn, fun ọja iwaju rere ipinlẹ naa.
No comments:
Post a Comment