Ẹ gba wa lọwọ awọn ajagungbalẹ o - Awọn araalu Adunbu Itori ke gbajare s'ijọba ipinlẹ Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, August 14, 2023

Ẹ gba wa lọwọ awọn ajagungbalẹ o - Awọn araalu Adunbu Itori ke gbajare s'ijọba ipinlẹ Ogun


Gbogbo awọn araalu Adunbu to wa ni Itori, ijọba ibilẹ Ewekoro, ipinlẹ Ogun ti pariwo sita, wọn si n rawọ ẹbẹ s'ijọba ipinlẹ naa labẹ iṣakoso Gomina Dapọ Abiọdun lati dide iranlọwọ fun wọn lori ọrọ awọn ajagungbalẹ ti wọn lo n fojoojumọ da wọn laamu.
 
Bẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni iroyin kan jade wi pe awọn ajagungbalẹ ya bo ile Baalẹ Adunbu, Oloye Kayọde Falọla, ti wọn si dana iya fun un. Wọn ṣa Baalẹ naa niṣakuṣa, to si jẹ  ori lo ko o yọ lọwọ iku ojiji, gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe sọ.
 

Lara awọn ti awọn ara agbegbe naa f'ẹsun kan ni Oloye Mutairu Owoẹyẹ, ẹni ti wọn lo n ran awọn tọọgi rẹ lati gbe ọkan awọn ara agbegbe naa gbona.
 
Opin ọsẹ to kọja yii l'awọn ara agbegbe Adunbun jade sita lọpọ yanturu, nibi ti wọn ti n ṣe iwọde ifẹhonuhan s'ijọba ipinlẹ Ogun, lodi si Owoẹyẹ, wọn ni awọn ko le sun oorun asundọkan mọ latigba ti wahala awọnn ajagungbalẹ ti bẹrẹ.

Nibi iwọde ifẹhonuhan naa ni wọn ti gbe oriṣiriṣi iwe alẹmode ti wọn ti n ko ye gbogbo awọn alẹnulọrọ n'ipinlẹ Ogun wi pe awọn mọto akọyẹpẹ ati katakata ni awọn ajagungbalẹ wa fi n gba ilẹ wọn lọna aitọ.


Lara rẹ si ni: "Ẹ dakun, ọrọ awọn ajagungbalẹ ti su wa ni Adunbu Itori", "Gomina Dapọ Abiọdun, ẹ gba wa lọwọ awọn ajagungbalẹ ni Adunbu", Ṣe Baba Owoẹyẹ ga ju ofin lọ ni? Gomina Abiọdun, ẹ dakun, ẹ gba wa ni Adunbu", "Ẹ gba wa lọwọ Owoẹyẹ, Mọjeed Ṣolabi, Nasiru ọmọ Owoẹyẹ, wọn ti fi tipa gbalẹ mọ wa lọwọ"
 
Iyawo Baalẹ, Arabinrin Balikis Falọla nigba to n sọrọ sọ pe "Oju oorun ni mo wa loru ọjọ Furaide mọjumọ Satide yẹn, ti mo fi n gbọ ariwo, ẹ kuro ninu ọgba mi. Aṣọ iro nikan lo wa lara mi lọjọ yẹn ti mo fi bọ sita.
 
"Wọn l'awọn fẹẹ ba Baalẹ sọrọ, a si sọ fun wọn pe ki wọn pada wa loju mọmọ. Bi ẹnikan ṣe sọrọ niyẹn pe awọn wa lati pa Baalẹ danu ni. Mo ṣe fidio gbogbo wọn, ti mo si n pariwo pe káwọn eeyan gba wa. Awọn ọmọ Owoẹyẹ ni wọn wa ka wa mọ inu ile. Bi mo ṣe n pe ọlọpaa naa ni mo n pe gbogbo awọn ti mo le pe loru yẹn.
 
"Wọn ti bẹrẹ sii ṣa Baalẹ, ẹjẹ sii ti kun gbogbo ilẹ. Wọn tun wọ inu ile lọ ba awọn ọmọ mi. Nibẹ ni wọn ti n jẹ ko ye wa pe ọga awọn Owoẹyẹ mọ si b'awọn ṣe wa, bẹẹ naa ni Nasiru mọ si. Wọn tun n pe Nasiru lori foonu wi pe awọn ti wa lọdọ wa. A fa ọrọ yii di nnkan bi aago mẹta oru.
 

"Wọn ba inu ile wa jẹ, wọn tun fọ gilaasi mọto. Ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira ti mo gbe sinu ile ni wọn gbe lọ. Ọsibitu ni mo ti wa ba a yin lonii. Ẹlẹẹkeji ti wọn maa wa ree. O ti su wa. ki ijọba gba wa."
 
Baalẹ naa, "Kayọde Falọla lorukọ mi, emi ni Baalẹ Adunbu, ọdun keje ree ti mo ti wa lori ipo Baalẹ. Inu ile ni mo wa ni nnkan bi aago mọkanla aabọ, ti mo fi ri ẹnikan ti wọn  n pe ni Atiku, o loun fẹẹ ri mi, mo si sọ fun un pe ilẹ ti ṣu, ko pada wa ti ilẹ ba ti mọ.
 
"Awọn ọmọ mi meji to wa lọdọ mi sọ fun un pe ko ma da mi laamu, nitori pe a ti fẹẹ lọ sun. Mi o mọ pe wọn pọ to bẹẹ, bi wọn ṣe ya wọnu ile niyẹn, ti wọn si bẹrẹ sii lu mi, wọn tun le awọn ọmọ mi. Igo ada, ọbẹ loriṣiriṣi ni wọn ko wa, mo ba bẹrẹ sii pariwo sita wi pe k'awọn ara adugbo gba mi.
 

"Gbogbo awọn to n wa sibẹ, igo ati okuta ni wọn n sọ lu wọn. Atiku sọ pe awọn ọga oun, Owoẹyẹ, Nasiru ati Mọjeed mọ si boun ṣe wa, o si bẹrẹ sii ba mi fa wahala. O mu kọkọrọ mọto mi, wọn tun lọ da ẹpọ inu jẹnẹretọ mi, wọn da epo to wa ninu ẹ, wọn gbe owo to wa ninu mọto mi.
 
"Miliọnu marun-un naira, owo ilẹ ti mo ṣẹṣẹ ta ni wọn gbe lọ. Wọn si ba mọto naa jẹ. Wọn lu mi, wọn ṣa mi, wọn de mi lọwọ ati l'ese, wọn wa gbe mi lọ si ikorita, nibi ti wọn ti lọ de mi mọ igi. Ibẹ ni wọn ti pe Mọjeed to wa l'ọgba ẹwọn wi pe awọn ti mu Baalẹ. Wọn la igi mọ mi lori, ariwo ti mo pa lo jẹ ki wọn salọ.


"Awọn aburo mi lo lọ gbe awọn ọlọpaa wa, ti wọn fi gbe mi lọ si teṣan, latibẹ ni mo gba de ọsibitu. Ọsibitu keji ree. Awọn mẹfa ti wa l'ahamọ ọlọpaa bayii, mo fẹ ki ijọba gba wa."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI