Bayii ni ijọba Kwara ṣe pin awọn ounjẹ iranwọ f'awọn araalu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, August 31, 2023

Bayii ni ijọba Kwara ṣe pin awọn ounjẹ iranwọ f'awọn araalu


Ijọba ipinlẹ Kwara ti pin awọn ounjẹ iranwọ fun gbogbo araalu patapata n'ipinlẹ naa, gẹgẹ bi ijọba apapọ orileede Naijiria ṣe paṣẹ.
 
Ojọru tii ṣe Wesidee, ọsẹ yii ni awọn igbimọ alakoso ti ijọba yan lati ṣagbatẹru pinpin awọn ounjẹ iranwọ naa bẹrẹ lai ṣe ojusaaju, to mu k'awọn araalu maa dupẹ.
 
Baagi irẹsi ti ko din ni ẹgbẹrun lọna igba ataabọ 250,000 ni wọn pin f'awọn araalu, paapaa awọn to ku diẹ kaato fun, lati jẹ ki wọn jẹ mudunmudun eto oṣelu awaarawa.

Ninu atẹjade ti akọwe iroyin igbimọ naa, Issa Muhammed fi sita, o ni ọjọ kejila, oṣu kẹjọ, ọdun 2023 ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq bura fun awọn ọmọ igbimọ naa pẹlu ileri wi pe wọn ko nii ṣe ojusaaju lori pinpin naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI