Baluwẹ ni Hammẹd ti f'ipa ja ibale ọmọ ọdun mọkanla l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, August 12, 2023

Baluwẹ ni Hammẹd ti f'ipa ja ibale ọmọ ọdun mọkanla l'Ogun


Pakopako ni gendekunrin, ọmọ ogun ọdun kan, Hammẹd Lawal n wo nigba tọwọ ọlọpaa tẹ ẹ lori ẹsun wi pe o f'ipa ja ibale ọmọdebinrin, ọmọ ọdun mọkanla kan ti a fi orukọ bo laṣiri.
 
Agbegbe Aiyepe Ijẹbu, ijọba ibilẹ Odogbolu, ipinlẹ Ogun ni wọn sọ pe Hammẹd ti f'ipa ja ibale ọmọ naa ninu baluwẹ, eyi gan-an lo n ya pupọ awọn eeyan lẹnu.
 
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ naa, Ọmọlọla Odutọla gbe jade sita lo ti jẹ ko di mimọ pe teṣan ọlọpaa ẹkun Odogbolu ni Hammẹd wa, nibi ti wọn ti n f'ọrọ wa lẹnu wo lọwọ.
 
O ni baba ọmọ naa to n gbe lojule karun-un, adugbo Aba Quarters lo lọ fi to awọn ọlọpaa Odogbolu leti wi pe Hammẹd f'ipa ja ibale ọmọ oun ninu baluwẹ.
 
Odutọla sọ pe baba naa jẹ ko di mimọ pe o ti pẹ ti Hammẹd ti maa n ba ọmọ oun ṣe ere egele, bo tilẹ jẹ pe ko sọ ọna to n gba to fi n dunkooko mọ ọn.
 
Siwaju si i lo jẹ ko di mimọ pe awọn ti mu ọmọ naa lọ ọsibitu fun ayẹwo ati igbaninimọran, to fi mọ itọju.


Bẹẹ lo sọ pe iwe ofin ọdaran, abala 218 fi han daju pe ẹwọn gbere lo wa fun ẹni to ba f'ipa ja ibalẹ ọmọdebinrin ti ko tii to ọdun mẹtala.
 
O wa fi kun un pe ọga awọn, Abiọdun Alamutu ti paṣẹ pe ki iwadii kikun bẹrẹ, ki wọn si rii daju pe idajọ ododo waye, nia fifoju rẹ ba ile-ẹjọ.
 
Bẹẹ ni ọga ọlọpaa Ogun rọ awọn obi ati alagbatọ lati maa mojuto awọn ọmọ wọn loore-koore.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI