Agboole Ọdọfin niluu Ijẹja, Abẹokuta ipinlẹ Ogun ti kede sita wi pe awọn ko fẹ Ọgbẹni Sunday Oluwọle n'ipo gẹgẹ bi Ọdọfin ilu Ijẹja, nitori awọn iwa aṣemaṣe to fi n d'oju ti wọn kaakiri.
Awọn mọlẹbi naa ninu lẹta ti agbẹjọro wọn, Amofin Kẹhinde Amusa ti Hassan Amusa Chamber kọ ranṣẹ si Alake ilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Gbadebọ; to fi mọ awọn alẹnulọrọ niluu Ẹgba lo ti kilọ fun Oluwọle lati dẹkun pipe ara rẹ ni Ọdọfin ilu naa, nitori pe awọn mọlẹbi ko lọwọ sii.
Ṣaaju asiko yii ni iroyin ti fi to wa leti pe awọn mọlẹbi naa ti jawe lọ rọkunle fun Oluwọle lori awọn iwa aṣemaṣe ti wọn fi kan an, eyi ti wọn lo lodi si ofin oye jijẹ niluu Ẹgba, paapaa ipinlẹ Ogun.
Wọn ni awọn ọrọ ti ko kan Oluwọle lo n da si laaarin ilu, eyi to le da alaafia ilu naa laamu, ti wọn si lo n tabuku ba orukọ agboole wọn.
Siwaju sii ni wọn sọ pe ọrọ nipa ipo Oluwo ilu Ijẹja wa nile ẹjọ lọwọ, ṣugbọn ti Oluwọle ko ronu nipa ẹ, to si n gbe igbesẹ to tako ẹsun to wa nile ẹjọ, eyi ti wọn ni ko bojumu to.
"Awa ti a jẹ gbẹnusọ fun agboole Ọdọfin niluu Ijẹja Abẹokuta ti awọn aṣoju wọn jẹ Alaaji Oloye Sẹmiu Lawal (Baalẹ abule Ọdọfin Village, Ijẹja Abeokuta; Alagba E. O. Ọlatomi, akọwe agboole Ọdọfin ljẹja ati Alaaji Surajudeen Lawal, Mufasir musulumi ilu Ijẹja) la n kede iyọni-n'ipo Sunday Oluwọle gẹgẹ bi aṣoju wọn nile Ogboni ilu Ijẹja.
"Ẹ wo iwe ipẹjọ ti ọjọ kẹwaa, oṣu kẹjọ, ọdun 2021. A n fẹ ki o dẹkun lati maa fi ara rẹ han gẹgẹ bi Ọdọfin ilu Ijẹja lati akoko yii lọ. Bi bẹẹ kọ, bi a ba kofiri rẹ nibi ti o ti n pe ara rẹ ni ohun ti o ko jẹ, a ko nii beṣubẹgba f'oju rẹ winna ofin"
Gbogbo akitiyan lati ba Oluwọle funra rẹ sọrọ lo ja si pabo titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin. Bi a ba si pada rii ba sọrọ, ohun to ba sọ la maa mu wa fun un yin.
No comments:
Post a Comment