Awọn meji laju sajule ọrun ninu ijamba ọkọ l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, August 12, 2023

Awọn meji laju sajule ọrun ninu ijamba ọkọ l'Ogun


Ko din ni eeyan meji ti wọn dagbere f'aye ninu ijamba ọkọ bọọsi to deedee gbokiti lori ere, iyẹ lagbegbe ile-epo Conoil to wa nitosi Interchange, opopona marosẹ Ekoo siluu Ibadan, ipinlẹ Ogun.
 
Yatọ si awọn meji to dagbere faye, awọn mẹta miran tun farapa, ti wọn si wa l'ọsibitu ti wọn ti n gba itọju titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
 
Agbẹnusọ ẹṣọ oju popona n'ipinlẹ Ogun, Babatunde Akinbiyi nigba to n ṣalaye f'awọn akọroyin, o sọ pe ori ere ni bọọsi eleri mejidinlogun naa wa, ko to o gbokiti lojiji, to si tun yiwọ wọnu koto.
 
Babatunde Akinbiyi sọ pe gbogbo awọn to ku ninu mọto ọhun ni ori ko yọ yato si awọn meji to ku, ati awọ mẹta to farapa.
 
O ni nọmba idanmọ mọto naa ni LGB 739 XA, ati pe nnkan bi aago mẹrin irọlẹ lo ṣẹlẹ, to si jẹ iyalẹnu nla f'awọn eeyan, paapaa awọn to wa legbegbe naa.
 
Akinbiyi sọ pe awọn oṣiṣẹ oju popona ti FRSC lo ko awọn oku naa lọ si mọṣuari ọsibitu Idẹra to wa ni Ṣagamu, bẹẹ naa l'awọn to farapa wa l'ọsibitu ọhun pẹlu fun itọju to pe ye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI