Orin ati ariwo ayọ nla lo gbe ẹnu pupọ awọn araalu ipinlẹ Kwara, paapaa awọn ọdọ nigba ti Gomina Abdulrahman AbdulRazaq kede Kọmureedi Ọlayinka Fafoluyi, ẹni ti ọpọ awọn eeyan mọ si Solace gẹgẹ bi amugbalẹgbẹ pataki f'ọrọ eto iroyin igbalode rẹ lẹẹkeji.
Solace ninu iṣakoso akọkọ ti Gomina AbdulRazaq jẹ amugbalẹgbẹ f'ọrọ eto iroyin igbalode, ṣugbọn to tun ti gba igbega bayii.
Ipo naa, Senior Special Assistant New Media ni wọn fun Solace, ẹni to ti fi gbogbo ọkan akikanju rẹ mu idagbasoke ati ilọsiwaju ba ipinlẹ naa.
Pupọ ohun t'awọn eeyan n sọ kaakiri bayii ni pe, igi to tọ ni gomina ki bọ inu iho to yẹ.
No comments:
Post a Comment