Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekoo ti f'oju gendekunrin, ẹni ọgbọn ọdun kan, Ṣọla Ṣẹgun ba ile ẹjọ Majisireeti to wa lagbegbe Ọjọ n'ipinlẹ naa, lori ẹsun wi pe o lu ẹnikan daku.
Kamọrudeen Ladi ni wọn pe orukọ ẹni ti Ṣẹgun lu daku, ko to di pe wọn foju rẹ ba ile-ẹjọ l'Ọjọ Ẹti tii ṣe Furaidee, ọsẹ yii.
Nigba to n fẹsun meji ọtọọtọ kan Ṣẹgun niwaju Onidajọ D.S. Odukọya, Agbefọba Esther Adesulu sọ pe ọjọ kin-in-ni, oṣu keje, ọdun ti a wa yii niṣẹlẹ ọhun waye ni ibudokọ First Gate to wa lagbegbe Iba, Ọjọ, ipinlẹ Ekoo.
Bo tilẹ jẹ pe Ṣẹgun sọ pe oun ko jẹbi pẹlu alaye, ati pe tu-faitin ni, ṣugbọn Adesulu sọ pe ẹsun naa lo tako iwe ofin ọdaran ipinlẹ naa t'ọdun 2015 ni abala 168 ati 173.
Adesulu ni ọrọ ti ko to nnkan lo ṣẹlẹ laaarin Ṣẹgun ati Ladi to n gbe lagbegbe Idi-Araba Oke-New Ire ni Ọjọ, to fi di pe o bẹrẹ sii lu, titi tiyẹn fi daku mọ ọn lọwọ nita gbangba.
O ni ẹṣẹ ti Ṣẹgun gba Ladi l'eti, lo jẹ ki eti rẹ bẹrẹ sii ṣẹjẹ titi to fi daku, to si ni ọsibitu ni Ladi ti pada laju.
Ninu ọrọ Onidajọ Odukọya, o ni ki wọn ṣi gba beeli Ṣẹgun na pẹlu ẹgbẹrun lọna igba naira, pẹlu oniduro meji, to si ni ki wọn tun ẹjọ naa gbe pada wa lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu keje, ọdun 2023.
No comments:
Post a Comment