Sanwo-Olu tun yan Gboyega Akọṣile gẹgẹ bi akọwe iroyin lẹẹkeji - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, July 4, 2023

Sanwo-Olu tun yan Gboyega Akọṣile gẹgẹ bi akọwe iroyin lẹẹkeji


Gomina Babajide Sanwo-Olu, t'ipinlẹ Ekoo tun ti pada yan Ọgbẹni Gboyega Akọṣile gẹgẹ bi akọwe iroyin rẹ ti yoo ba a ṣiṣẹ papọ fun saa iṣakoso keji to bẹrẹ laipẹ yii.
 
Akọṣile la gbọ pe Gomina Sanwo-Olu ti lo fun saa akọkọ rẹ, to si ni iṣẹ ọkunrin naa tẹ oun lọrun, idi toun fi tun pada yan-an s'ipo naa lẹẹkeji, paapaa julọ fun idagbasoke eto iṣejọba rẹ.
 
Yatọ si Akọṣile, Sanwo-Olu tun yan Tayọ Ayinde gẹgẹ bi olori awọn oṣiṣẹ rẹ lẹẹkeji; Ọgbẹni Gboyega Ṣoyannwo, gẹgẹ bi igbakeji olori awọn oṣiṣẹ ati Amofin Bimbọla Salu-Hundeyin, gẹgẹ bi akọwe ijọba.
 
Ninu atẹjade ti olori awọn oṣiṣẹ ijọba, Ọgbẹni Hakeem Muri-Okunọla gbe jade laipẹ yii, lo ti sọ pe iṣẹ awọn eeyan naa bẹrẹ loju ẹsẹ lai si idaduro kankan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI