Ọpẹyẹmi digun wo ile-onile loru ọganjọ, lo ba ji foonu gbe - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, July 8, 2023

Ọpẹyẹmi digun wo ile-onile loru ọganjọ, lo ba ji foonu gbe


Ọjọru ti i ṣe Wẹsidee, ọsẹ to n bọ ni gendekunrin, ẹni ọdun mejidinlọgbọn kan, Ọlatunde Ọpẹyẹmi yoo tun pada f'oju ba ile-ẹjọ lori ẹsun idigunjale ti wọn fi kan niluu Ado-Ekiti, ipinlẹ Ekiti.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, nnkan bi iaajo meji oru, ọjọ keji, oṣu keje, ọdun ti a wa yii ni Ọpẹyẹmi lo digun ile obinrin kan ti wọn pe ni Iyabọde Musa to wa lagbegbe Okesa, Ado-Ekiti.
 
Wọn ni boun pẹlu ẹnikeji rẹ toun ti na papa bora ti digun wọle naa, ni wọn ti gbe Firiiji ti owo rẹ jẹ ẹgbẹrun lọona aadọfa naira, foomu ibusun ti owo rẹ jẹ ẹgbẹrun lọna ogoji naira ati bẹẹdi onirin ti owo rẹ jẹ ẹgbẹrun lọna ogun naira.
 
Agbefoba, Sọdiq Adeniyi too fẹsun kan Ọpẹyẹmi ṣalaye niwa ile-ẹjo wi pe apapọ gbogbo ohun ti ọmọkunrin naa ji jẹ ẹgbẹrun mẹwaa le igba naira, N210,000.
 
Nigba to n tako o lọjọ Ẹti, Furaidee to kọja yii, o ni ẹsun toun fi kan Ọpẹyẹmi tako iwe ofin ọdaran ti abala 322 (a) (b) (c), 323 (1) ati (2), to fi mọ abala 302 ninu iwe ofin ọdaran ipinlẹ naa, tọdun 2021.
 
Onidajọ Ọlawunmi Olowolafẹ nigba toun naa n sọrọ sọ pe ki wọn gba beeli Ọpẹyẹmi pẹlu ẹgbẹrun lọna aadọta naira, ati oniduro kan to n san owo ori rẹ deedee.
 
Bẹẹ lo sun igbẹjọ siwaju d'ọjọ kejila, oṣu keje, ọdun yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI