Ko si ọrọ meji to n lọ kaakiri ori ikanni ayelujara lorileede Naijiria lasiko yii, to kọja ọlọpaa kan ti gbajugbaja olorin Afrobeat nni, Ṣeun Kuti gba leti niluu Ekoo ni nnkan bi ọsẹ meloo kan sẹyin, eyi ti ileeṣẹ ọlọpaa ti wa a pada fun un ni igbega lẹnu iṣẹ rẹ.
Mohammed Aminu lorukọ ọlọpaa ọhun.
Ninu fọnran naa to kaakiri nigba naa, la ti ri Ṣeun Kuti to ti gba ọlọpaa ọhun leti, to si tun n leri wi pe oun yoo lu lalubolẹ, iyẹn ninu oṣu karun-un, ọdun yii.
Ninu atẹjade ti ileeṣẹ ọlọpaa gbe jade, wọn l'awọn ti fun ọkunrin naa ni igbega, nitori to mọ iṣẹ rẹ gẹgẹ bi iṣẹ, ati pe o n ṣiṣẹ rẹ pẹlu otitọ ati igbagbọ to ni ninu iṣẹ naa.
Ipo Assistant Superintendent of Police (ASP) la gbọ pe wọn fun Aminu.
Agbẹnusọ ọlọpaa to n ri sọrọ igbega, Ikechukwu Ani, nigba to n sọrọ sọ pe awọn fẹran bi ọkunrin naa ṣe n ṣiṣẹ rẹ.
Yatọ si eyi, o ni awọn tun ti fun awọn ọlọpaa miran ni igbega lẹnu iṣẹ wọn, ti apapọ gbogbo wọn si le ni ẹgbẹrun lọna ogun.
No comments:
Post a Comment