Ọjọ kan pere lo ku ki Adebọwale ṣegbeyawọ alarinrin niluu Ẹdẹ, ni aṣita ibọn ba ran-an lọ sọrun l'Ọṣun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, July 3, 2023

Ọjọ kan pere lo ku ki Adebọwale ṣegbeyawọ alarinrin niluu Ẹdẹ, ni aṣita ibọn ba ran-an lọ sọrun l'Ọṣun


Iroyin ti ko dun mọ ẹnikẹni ninu rara ni bi wọn ṣe sọ pe aṣita ibọn ba ọkọ iyawo oju ọna ti wọn pe orukọ rẹ  ni Adebọwale Toromade, to si gbabẹ sọda sọrun alakeji.
 
Ilu Moro to wa n'ijọba ibilẹ Ifẹ-North ni wọn sọ pe iṣẹlẹ ọhun ti waye l'ọsẹ to ṣẹṣẹ kọja tan yii.
 
AWIKONKO gbọ pe iyawo afẹsọna Adebọwale wa ninu oyun, ti wọn si ti n gbaradi fun eto ayẹyẹ mọmi-n-mọ-ẹ laaarin mọlẹbi rẹ ati mọlẹbi iyawo to fẹẹ fẹ naa, eyi si ni yoo jẹ ki wọn tete ṣegbeyawọ alarinrin ti wọn ti n palẹmọ rẹ.

Wọn ni ile awọn mọlẹbi iyawo afẹsọna rẹ to wa lagbegbe Edunabọn to wa ni Ifẹ North ni Adebọwale ti n bọ lọjọ naa. Bo si ṣe de, ni wọn lo ya ni ikorita Moro lati b'awọn ọlọkada ẹgbẹ rẹ ṣajọyọ awọn adari tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan.
 
Ibi ti wọn ti n ṣajọyọ ọhun lọwọ la gbọ pe awọn kan ti dabọn bolẹ, to si mu ki ipejọpọ naa tuka, wọn l'awọn eeyan sa asala fun ẹmi ara wọn, to si jẹ iyalẹnu pe nibi ti Adebọwale naa ti n salọ ni aṣita ibọn ti ba a, to si gbabẹ sọda sọrun alakeji.
 
A tiẹ gbọ pe awọn meji ni ibọn ba lọjọ naa, ṣugbọn ti wọn sọ pe ẹnikeji ṣi n gba itọju lọwọ lọsibitu. 

Yẹmisi Ọpalọla to jẹ agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, to si jẹ ko di mimọ pe iwadii awọn ti bẹrẹ lati rọwọ to gbogbo awọn to mọ nipa iṣẹlẹ ọhun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI