Awujalẹ nigba toun naa n sọrọ jẹ ko di mimọ pe ajọṣepọ to wa laaarin oun ati Tinubu kọja ohun ti ẹnikẹni le lero, nitori pe awọn ti jọ wa tipẹ.
Ọba
Adetọna sọ pe oun wa lara awọn to fẹyin pọn Tinubu lasiko ti wọn fẹẹ le
awọn ṣọja kuro nile ijọba lọjọsi, to si ni idi rẹ niyẹn ti wọn fi n pe
oun ni Baba NADECO.
Siwaju sii lo sọ pe oun wa
lẹyin Tinubu lati lo ọdun mẹjọ gbako lori ipo Aarẹ Naijiria, nitori pe
awọn igbesẹ rẹ ti fi han daju pe Ọlọrun lo yan an lati gbe Naijiria de
ilẹ ileri ti awọn awọn araalu n fẹ
Lara awọn
to wa nibẹ ni Gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun; Olori awọn oṣiṣẹ Aarẹ,
Ọnarebu Fẹmi Gbajabiamila, Gomina tẹlẹri n'ipinlẹ Ogun, Oloye Oluṣẹgun
Ọṣọba; oludamọran pataki si aarẹ lori eto aabo, Nuhu Ribadu; ati Dele
Alakẹ toun jẹ oludamọran pataki lori eto ikansira-ẹni.
Aare orileede Naijiria, Bọla Ahmẹd Tinubu ti sọ pe ẹmi Awujalẹ toun gbe wọ lasiko eto idibo ọdun 2023 lo mu koun bori ninu eto idibo naa.
Tinubu lo sọrọ naa niluu Ijẹbu-Ode, lasiko to ṣabẹwo si Ọba Sikirulai Adetọna, Awujalẹ tilẹ Ijẹbu, ipinlẹ Ogun.
Aarẹ Tinubu lo ṣabẹwo si ipinlẹ Ogun lati dupẹ lọwọ awọn ọba fun ipa ti wọn ko lasiko eto idibo apapọ ọdun 2023, eyi to gbe e wọle gẹgẹ bi aarẹ.
Tinubu to balẹ si papa iṣere Dipọ Dina to wa niluu Ijẹbu-Ode ni deedee aago mẹwaa kọja iṣẹju mẹtadinlogun ninu ọkọ Baluu agberapa tijọba apapọ, eyi ti nọmba idanimọ rẹ jẹ 5N FG2.
Lẹyin naa lo tẹkọ leti lọ si Aafin Awujalẹ.
Bi Tinubu ṣe de aafin Awujalẹ lo ti wọle lọ lati ba Kabiyesi naa ṣe ipade ikọkọ, eyi ti wọn ko gba awọn akọroyin laaye lati wọle.
Ṣugbọn nigba to n sọrọ lẹyin ipade naa, Aarẹ Tinubu jẹ ko di mimọ pe niṣe loun wa fi ẹmi imoore han si ọba naa fun ipa to ko lori aṣeyọri oun.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe
"Ipinlẹ Ogun ni mo ti gbe ẹmi itusilẹ wọ. Ile ni mo pada wa, mo si jẹ yin ni ọpọlọpọ nnkan, paapaa lati dupẹ lọwọ yin.
"Nitori ọna ti ẹ gba lati dide si mi lati gba mi, mi o mọ ohun ti mo tun le sọ ju pe ẹ ṣeun.
"Si ọpọ ninu yin, ẹ ṣeun ti e duro ti ni, ti ẹ si tun duro ti Naijiria. Ẹ fi ifẹ otitọ ati ifarajin han, debu wi pe ẹ dibo lasiko ipenija.
"Wọn gbe owo yin pamọ, wọn ko jẹ ki ẹ ri owo na. Owo ti paarọ ko pada ṣiṣẹ. Nigba ti mo ri igbesẹ yii, mo wa si ipinlẹ Ogun lati gbe ẹmi itusilẹ ati akikanju, eyi ti wọn mọ wa si wọ.
"Ẹẹmeji ọtọọtọ ni mo gbe ẹmi naa wọ. Ẹmi Baba (Awujalẹ). Ẹmi Baba – Emi l’okan. Iyẹn ni ti Baba. Nitoru pe niṣe ni Baba maa n sọ oju abẹ nikoo , bi Baba ṣe ri niyẹn.
"Ẹmi keji ni ti ẹmi owo to mu mi sọ pe 'A maa dibo, a maa wọle', koda lasiko ti ko si owo nita. Latigba naa lo ti jẹ pe awọn ẹmi yii lo ti n fun mi ni okun lati sin orileede yii."
No comments:
Post a Comment