Ọrọ buruku toun tẹrin nigba ti baale ile, ẹni ọdun mejilelogoji kan, Chukwuemeka Nwachukwu, ti wọn foju rẹ ba ile-ẹjọ lori ẹsun wi pe o lu pasitọ ni jibiti miliọnu kan naira loun ko jẹbi pẹlu alaye, ṣugbọn ti adajọ sọ pe ko ṣi fi alaye rẹ pamọ fun igba miran na.
Nwachukwu, nigba to n f'oju ba ile-ẹjọ Majisireeti l'Ọjọ Ẹti, Furaide, ọsẹ yii ni wọn lo fi ọgbọn iwa jibiti gba owo lọwọ Pasitọ Oliver Ogbuagu, pẹlu ẹtanjẹ lati baa ra bọọsi Volkewagen T4.
Agbẹjọrọ to fẹsun kan Nwachukwu ṣalaye pe ọjọ kẹjọ, oṣu lọkanla, ọdun 2022 lọkunrin naa gba owo ọhun lọwọ Pasitọ naa lagbegbe Ilogbo to wa ni Ọjọ, l'Ẹkoo.
O ni bi Nwachukwu ṣe gba owo naa tan, niṣe lo bẹrẹ sii f'owo naa jaye familete-ki-n-tutọ kaakiri igboro, ti ko si ra bọọsi ọhun.
Wọn ni gbogbo bi Pasitọ naa ṣe n beere owo rẹ ati bọọsi naa lọwọ Nwachukwu, lo fi oni da oni, ati ọla da ọla, ko to di pe Pasitọ naa gba teṣan ọlọpaa lọ lati fi to wọn leti.
Agbẹjọro naa wa sọ pe ẹsun yii lo tako iwe ofin ọdaran ipinlẹ Ekoo t'ọdun 2015 ni abala 287 ati 314.
Onidajọ D.S. Odukoya sọ pe ki wọn pada wa lọjọ kẹwaa, oṣu kẹwaa, ọdun 2023 ti igbẹjọ yoo tun waye, ati pe anfaani wa lati gba beeli Nwachukwu pẹlu idaji miliọnu naira ati oniduro meji ọtọọtọ.
No comments:
Post a Comment