Nitori igba naira ti ko fun wọn, oṣiṣẹ aṣọbode yinbọn pa ọlọkada l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, July 11, 2023

Nitori igba naira ti ko fun wọn, oṣiṣẹ aṣọbode yinbọn pa ọlọkada l'Ogun


Niṣe lọrọ di boolọ o yagọ lọna lagbegbe Idigbo to wa n'ijọba ibilẹ Ariwa Yewa, ipinlẹ Ogun l'ọsẹ to kọja yii nigba ti oṣiṣẹ aṣọbode ti Nigeria Immigration Services yinbọn pa ọkunrin ọlọkada kan.
 
Owo riba ti ko ju igba niara pere lọ ni iroyin fi to wa leti wi pe o da wahala silẹ lọjọ naa
 
Lara awọn to fi iṣẹlẹ ọhun to wa leti sọ pe ọlọkada naa, Jacob Bamgbọla lo n gbe aburo ẹgb'ọn rẹ lọ lori ọkada, ko to di pe awọn oṣiṣẹ aṣọbode naa daa duro lagbegbe Ijowun to kọgun igbẹyin Idiroko.

A gbọ pe bi wọn ṣe daa duro, ni wọn ti n beere owo lọwọ ẹ, ti wọn si lawọn yoo gba igba naira ko to le kọja lọ si ibi to n lọ, eyi lo bii ninu wi pe oun ko ni owo kankan lati san fun wọn.

Nibi ti wọn ti n fa ọrọ naa, l'awọn miran to n kọja lọ ti de ba wọn nibẹ, ti wọn si n gba owo lọwọ wọn, igbe ti wọn sọ pe Bamgbọla rii pe wọn ko kọbi ara soun, lo jẹ ko ba ẹsẹ rẹ sọrọ, to si lọ ṣalaye f'awọn ara adugbo to lọ.

Ibinu yii ni wọn l'awọn ọdọ fi ko arawọn jọ, ti wọn si lọ fẹhonuhan nile ọkan lara awọn agba agbegbe naa, Oloye Moses Falẹyẹ.

Nibi ti wọn ti n fẹhonuhan la gbọ pe awọn oṣiṣẹ aṣọbode naa ti de ba wọn nibẹ, ti wọn si dabọn bolẹ lati le gbogbo wọn danu. Nibi ti awọn eeyan naa ti n sa asala fun ẹmi ara wọn la gbọ pe ọkan lara awọn oṣiṣẹ aṣọbode ti wọn pe ni Lamba ti yinbọn fun Bamgbọla, tiyẹn si ku loju ẹsẹ.
 
A tiẹ gbọ pe wọn gbiyanju lati du Bamgbọla, ko maa dakẹ, ṣugbọn oju ọna ọsibitu ti wọn n gbe e lọ lo ti dakẹ mọ wọn lọwọ.
 
Olori awọn oṣiṣẹ aabo fijilante lagbegbe naa, Adeṣina Alabi ninu ọrọ rẹ naa fẹsun kan awọn oṣiṣẹ aṣọbode yii lori bi wọn ṣe n gba owo aitọ lọwọ awọn to ba n kọja lọ.
 
Yatọ si awọn NIS yii, wọn lawọn ọlọpaa, kọsitọọmu, at'awọn miran naa tun n gba owo aitọ lọwọ awọn eeyan ni gbogbo agbegbe ọhun, ti wọn si ni ko bojumu to.
 
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Ọmọlọla Odutọla ninu ọrọ rẹ ṣalaye pe oun ko tii gbọ nipa iṣẹlẹ naa, ati pe oun yoo sọ bi iṣẹlẹ ọhun ṣe lọ lẹyin iwadii.
 
Bakan naa ni Ọlajide Ọṣhifẹsọ to jẹ agbẹnusọ f'awọn NIS nipinlẹ Ogun sọ pe awọn ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI